Agbekalẹ 'Owo Iṣowo' ni lati dẹkun iṣẹ ati oṣi laaarin ilu - Rukayat Shittu - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Thursday, September 22, 2022

Agbekalẹ 'Owo Iṣowo' ni lati dẹkun iṣẹ ati oṣi laaarin ilu - Rukayat Shittu


Oludije s'ipo ọmọ ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Kwara labẹ asia ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC, Rukayat Motunrayọ Shittu ti sọ pe erongba ati agbekalẹ 'Owo Iṣowo' to n lọ lọwọ lasiko yii ni lati dẹkun iṣẹ ati oṣi laaarin ilu.

Rukayat Shittu to jade lati agbegbe Owode Onire lo sọrọ yii nibi eto 'Owo Iṣowo' ti ijọba pin f'awọn araalu lati fi kun owo ti wọn fi n ta ọja, lati le jẹ ki eto ọrọ aje wọon dagbasoke.
 
Ileeṣẹ ti wọn pe ni Kwara State Social Investment Programme (KWASSIP)’, ti awọn eeyan tun mọ si Owo Iṣowo ni banki agbaye ṣagbatẹru ẹ, ti ijọba ipinlẹ naa si ṣakoso pinpin rẹ. 
 
Nigba to n sọrọ nibi ti wọn ti n pin owo naa lagbegbe Alapa, ijọba ibilẹ Asa, o ni ọna lati ṣe iranwọ f'awọn olokoowo kekeeke, ki awọn naa le jẹ mudunmudun eto iṣejọba awaarawa.
 
O wa gba awọn araalu lamọran, paapaa awọn to lanfaani si owo naa lati lo o s'ori okoowo wọn tabi iṣẹ ti wọn yan laayo, ko le ba a so eso rere fun wọn lọjọ iwaju.
 
Bakan naa lo gbe oṣuba kare fun Gomina AbdulRahman AbdulRazaq lori awọn iranwọ to n ṣe f'awọn araalu, paapaa awọn obinrin to jẹ anfaani naa.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI