Agbaṣẹṣe to fẹẹ lu ijọba Kwara ni jibiti obitibiti owo dero atimọle - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Friday, September 23, 2022

Agbaṣẹṣe to fẹẹ lu ijọba Kwara ni jibiti obitibiti owo dero atimọle


Ọwọ ileeṣẹ ọlọpaa ti tẹ agbaṣẹṣe kan ti wọn lo fẹẹ lu ijọba ipinlẹ Kwara ni jibiti owo to din diẹ ni aadoje miliọnu, N138m naira lori akanṣe iṣẹ ti wọn gbe lee lọwọ

Awọn ẹrọ amunawa ti tiransifọma (transformer) ti ko din ni marundinlogoji la gbọ pe agbaṣẹṣe naa ba ijọba ipinlẹ Kwara tọwọ bọwe adehun lati ko wa fun wọn, ti a si gbọ pe ẹni naa ti gba N138m lati fi bẹrẹ iṣẹ.
 
Wọn ni bi ẹni naa ṣe gba owo yii, lo bẹrẹ sii jaye familete kin tutọ kaakiri, ti ko si ṣiṣẹ ti ijọba gbe lee lọwọ.

Ọrọ yii lo ti wa n da ariyanjiyan silẹ nigboro ipinlẹ naa, ti awọn kan si n sọ pe ṣe ni ijọba fi iṣẹ naa lu awọn araalu ni jibiti.
 
Bi ọrọ si ṣe n lọ kaakiri igboro, ni wọn sọ pe ijọba ranṣẹ pe agbaṣẹṣe naa lati wa a sọ idi ti ko fi mu awọn adehun rẹ ṣẹ, ṣugbọn ti wọn lo kọ jalẹ lati yọju, eyi lo mu ki ijọba fi ọrọ naa to awọn ọlọpaa leti, ti wọn si bẹrẹ iṣẹ.

Ileeṣẹ to n sọrọ ina ijọba ileeṣẹ eto idajọ, iyẹn Ministries of Energy and Justice la gbọ pe wọn gba ileeṣẹ ọlọpaa lọ lati fi to wọn leti, ko ti di pe wọn lọ gbe agbaṣẹṣe naa.
 
Bẹ o ba gbagbe, l'ọsẹ bii meloo kan sẹyin la gbọ pe ọwọ kọkọ tẹ agbaṣẹṣe ọhun, ti wọn si tii mọle, ṣugbọn to pada ri aanu gba nipa beeli ti wọn gba fun un, lẹyin to ṣeleri wi pe oun yoo bẹrẹ iṣẹ naa.

Lẹyin to gba itusilẹ la tun gbọ pe ọkunrin naa ko tun gbe igbesẹ kankan lati ṣiṣẹ to ti gba owo rẹ, eyi lo jẹ ki wọn tun lọ pada gbe e l'ọjọ Iṣẹgun, Tusidee to kọja yii, ti wọn si f'oju rẹ ba ile ẹjọ majisireeti to wa niluu Ilọrin, nibi to ti kawọ pọyin rojọ.
 
Ni bayii, ile ẹjọ ti wa sun igbẹjọ siwaju di ọjọ kejidinlogun, oṣu kẹwaa, ódun ti a wa yii.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI