Agba ofifo lasan ti ko lomi ninu ni Saraki - Wike ju bọmbu ọrọ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Friday, September 23, 2022

Agba ofifo lasan ti ko lomi ninu ni Saraki - Wike ju bọmbu ọrọ


Gomina ipinlẹ Rivers, Nyesom Wike ti bu ẹnu atẹ lu aarẹ ile igbimọ aṣofin agba orileede Naijiria tẹlẹ, Sẹnetọ Bukọla Saraki, to si ni agba ofifo lasan ti ko lominu lasan lo jẹ, paapaa n'ipinlẹ Kwara.
 
Wike, ẹni to tun jẹ adije s'ipo aarẹ Naijiria labẹ asia ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party, PDP, ṣugbọn to pada fidi rẹmi nibi idibo abẹle sọ pe Saraki ko le gbe apoti ibo ni wọọdu to ti wa, ki wọn dibo fun un.
 
Bakan naa lo ṣapejuwe Saraki gẹgẹ bi ọkọ taisi, ti ko ni garaaji ti yoo duro si.

Siwaju si i lo jẹ ko di mimọ pe gbogbo erongba alaga ẹgbẹ oṣelu PDP lapapọ, Iyorchia Ayu ni lati di akọwe ijọba orileede yii, iyẹn bi Alaaji Atiku Abubakar ba jawe olubori ninu idibo to n bọ lọdun 2023.

Wike tun f'idi rẹ mulẹ pe ipo akọwe agba lorileede yii ti Ayu n le naa ni Saraki n le, to si l'awọn mejeeji n tan ara wọn jẹ lasan ni, nitori pe ipinnu wọn ko le wa si imuṣẹ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI