Gomina ipinle Kwara, AlbdulRahman AbdulRazaq tun ti kede awọn amugbalẹgbẹẹ mẹta miran ti yoo maa ba a ṣiṣẹ, ki saa iṣejọba to n lọ lọwọ yii too pari.
Ọjọ Iṣẹgun, Tusidee ana ni Gomina kede awọn mẹtẹẹta sita fun gbogbo awọn ọmọ ati olugbe ipinlẹ naa lati mọ.
Awọn amugbalẹgbẹẹ tuntun mẹta wọnyi ni meji ninu wọn nii ṣe pẹlu ọrọ alaafia nipa ẹlẹyamẹya, ti ẹnikan yooku si jẹ amugbalẹgbẹẹ lori ọrọ ikansira-ẹni.
Lara awọn reyan naa ni Amofin Chukwugozie Angus Igwebuike, to jẹ amugbalẹgbẹẹ gomina lori ọrọ to nii ṣe pẹlu ẹya Igbo (Intercommunity Relations), Muhammed Abdullahi si jẹ amugbalẹgbẹẹ lori ọrọ to nii ṣe pẹlu ẹya Fulani.
Ẹnikan yooku ni gbajugbaja akọroyin nipinlẹ naa, Ibraheem Abdullateef Kọlawọle, toun jẹ amugbalẹgbẹẹ lori ọrọ to nii ṣe pẹlu eto ikansira-ẹni.
Awọn mẹtẹẹta yii la gbọ pe wọn yoo ṣe daadaa ni ẹka ileeṣẹ ti wọn ti gbe iṣẹ le wọn lọwọ.
No comments:
Post a Comment