Oludije s'ipo gomina ipinlẹ Ogun labẹ asia ẹgbẹ oṣelu African Action Congress, AAC, Ọnarebu Harrison Adeyẹmi ti jẹ ko di mimọ pe ẹgbẹ naa nikan ni ọna abayọ si iṣejọba awaarawa to lọọrin, paapaa n'ipinlẹ naa.
Laipẹ yii ni Ọnarebu Harrison Adeyẹmi sọrọ naa jade niluu Abigi, ijọba ibilẹ Ogun Waterside, iyẹn nibi ayẹyẹ igbade ọdun karun-un ti Ojotumoro tilu Abigi, Ọba Oluṣẹgun Ogunye.
Nibẹ ni Ọnarebu Adeyẹmi ti sọ pe afi ki awọn ara, ọmọ ati olugbe ipinlẹ Ogun lọ maa gbaradi lati le iṣakoso ẹlẹtan ti APC danu lọdun 2023, nitori pe wọn ko fẹran araalu.
O ni ẹgbẹ oṣelu AAC toun jẹ aṣoju wọn fun ipo gomina nipinlẹ naa nikan lo nifẹẹ araalu lọkan, ati pe eto ti yoo ṣe ojurere s'awọn eeyan l'awọn ni nilẹ.
Harrison to ti figba kan ri jẹ ọmọ ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Ogun fi kun ọrọ rẹ pe ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party, PDP ati ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC ti ja awọn ọmọ orileede Naijiria kulẹ lọna to kọja oye ẹnikẹni.
Idi ree to fi ni asiko to lati le wọn danu kuro ni ijọba, ki wọn si yan awọn adari to ni erongba rere fun orileede yii, paapaa ipinlẹ Ogun.
Bẹẹ lo fi kun ọrọ rẹ pe ọjọ iwaju awọn araalu, paapaa awọn ogowẹẹrẹ to n bọ lẹyin lo jẹ oun logun, ati pe gbogbo eto lo ti wa nilẹ lati daabobo ẹmi ati dukia araalu.
No comments:
Post a Comment