Bi iroyin to tẹ AWIKONKO lọwọ laipẹ yii ba fi jẹ otitọ, a jẹ pe nnkan ko lọ daadaa laaarin oludije s'ipo aarẹ labẹ asia ẹgbe oṣelu Peoples Democratic Party, PDP, Alaaji Atiku Abubakar ati olori ẹgbẹ naa n'ipinlẹ Kwara, Abubakar Bukọla Saraki lori ipo alakoso ipolongo eto idibo rẹ.
Ohun ti a gbọ ni pe Saraki l'awọn eeyan n f'oju sọna fun tẹlẹ wi pe Atiku fẹẹ lo fun alakoso eto ipolongo idibo rẹ, ṣugbọn ti wọn ni ẹkun Iwọ-Oorun ni Atiku n f'oju sọna fun bayii lati mu alakoso rẹ.
Iroyn ti a gbọ ni pe awọn meji ti Atiku n f'oju sọna fun lati kede sita ni gomina ipinlẹ Ọyọ, Onimọ-ẹrọ Ṣeyi Makinde ati gomina tẹlẹ n'ipinlẹ Ọṣun, Ọlagunsoye Oyinlọla
Eyi la gbọ pe o n fa ọpọlọpọ rukerudo ninu ẹgbẹ oṣelu PDP n'ipinlẹ naa lakoko yii, ti nnkan ko si lọ deedee.
Wọn ni gbogbo erongba Saraki ni pe oun ni Atiku yoo lo fun ipo alakoso eto ipolongo, lojuna lati ri owo ti yoo na fun eto oṣelu ipinlẹ Kwara to n bọ lọna, ki ẹgbẹ naa le jawe olubori.
No comments:
Post a Comment