Oluwo ti ilu Iwo, Ọba Abdulrasheed Adewale Akanbi, Telu kin-ni-in ti sọ pe bi ọmọ ni oludije sipo aarẹ orileede yii labẹ asia ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC, Aṣiwaju Bọla Ahmed Tinubu ṣe jẹ si oun.
Kabiyesi naa sọrọ yii lori ikanni ayelujara ti fesibuuku rẹ laipẹ yii, lakoko to fi fọto oun pẹlu Tinubu sita.
Ninu ọrọ to kọ sabẹ fọto ọhun, Oluwo ni ọmọ oun ni Tinubu jẹ gẹgẹ bi ọmọ Yoruba, ati adari iran Yoruba, to tun jẹ alẹnulọrọ lorileede Naijiria.
Bakan naa ni Kabiyesi rọ awọn eeyan lati gbaruku ti ipinnu Tinubu, ẹni to tun jẹ aṣiwaju ẹgbẹ oṣelu APC lapapọ.
No comments:
Post a Comment