Alaṣẹ ati oludasilẹ ṣọọṣi Deeper Christian Life Ministry, Pasitọ William Kumuyi ti sọ ọ nita gbangba wi pe Ọlọrun ti ṣetan lati dun awọn ọmọ orileede Naijiria ninu, nitori pe Oun nikan lo le sọ ẹni ti aarẹ orileede yii yoo jẹ lọdun 2023.
Pasitọ Kumuyi jẹ ko di mimọ pe awọn ọmọ Naijiria yoo kun fun ayọ rẹpẹtẹ lẹyin idibo ọdun 2023, nitori pe ileri Oluwa Ọga Ogo ni yoo ṣẹ.
Inu aafin Osemawe tilu Ondo, Ọba Victor Kiladejọ ni Pasitọ Kumuyi ti sọrọ idaniloju naa l'Ọjọru, Wẹside to kọja yii.
"Njẹ eto idibo maa waye lọdun to n bọ? Njẹ eto idibo ko nii le waye? Taa ni yoo jawe olubori lati di aarẹ orileede wa? Taa ni yoo jabọ ninu awọn gomina ipinlẹ kọọkan? Ọlọrun ti mọ ọn ko to to asiko, ṣugbọn a ṣi n fẹ iyanju si iṣoro awọn eeyan to n ṣẹlẹ latigbadegba nilẹ wa.
"Ohun ti Ọlọrun n fẹ ni yoo pada ṣẹlẹ, ko si eku to le duro loju ona, to le sọ pe enikan ko le kọja.
"Bi Ọlọrun ba sọ pe nnkan toun fẹ ree, paapaa fun Naijiria, paapaa fun ọdun 2023, ko si Eerin (Elephant) eeyan to le duro loju ọna rẹ. Ifẹ Ọlọrun ni yoo ṣẹ, ti gbogbo wa si maa kun fun ayọ."
No comments:
Post a Comment