Iroyin to tẹ wa lọwọ laipẹ yii ti f'idi rẹ mulẹ pe awọn araalu ti yẹyẹ oludije s'ipo gomina labẹ asia ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party, PDP n'ipinlẹ Kwara, Shuiab Yaman.
Ko si nnkan meji ti wọn lo fa a ti wọn fi yẹyẹ Yaman bi ko ṣe ti owo ti wọn lo ko kalẹ lati fi ran awọn to padanu dukia wọn sinu ijamba ina to waye ninu ọja Alanamu to jona.
AWIKONKO gbọ pe latigba ti ẹgbẹ oṣelu PDP ti fa Yaman kalẹ gẹgẹ bi oludije wọn, lo ti kuro n'ipinlẹ Kwara, ti wọn si ni ko sẹni to le sọ ibi to lọ.
Bo tilẹ jẹ pe a ko le f'idi rẹ mulẹ, wọn ni gbogbo b'awọn eeyan ṣe n wa a lati ri, ni ko sẹni to le sọ pato ibi ti wọn le wa a si.
Nigba ti wọn maa gburo rẹ, a gbọ pe ọsẹ bii mẹta lẹyin ti ọja naa jona lo ṣẹṣẹ yọju, iyẹn lẹyin t'awọn eeyan bẹrẹ sii pariwo orukọ rẹ wi pe ko laanu araalu.
Wọn ni ẹgbẹrun lọna ẹẹdẹgbẹrin naira ni Yaman ko silẹ f'awọn ti dukia wọn jona lẹyin ti wọn fi agidi mu, eyi ti wọn ni ko ka nnkankan. Ẹgbẹrun marun-un-marun-un naira ni wọn kan ẹnikọọkan ninu awọn to padanu ọja wọn naa.
Bakan naa la gbọ pe abẹwo ti Yaman ṣe sibẹ ko bu iyi ku oludijo s'ipo gomina, paapaa ẹni to yẹ ko jẹ adari.
No comments:
Post a Comment