Gomina ipinlẹ Ọyọ, Onimọ-ẹrọ Ṣeyi Makinde ti sọ pe oun ko ni i gba gbogbo awọn ọta ipinlẹ naa laaye lati ṣe aṣeyọri, to si ni gbogbo wọn pata lo maa kabamọ pe wọn n tako idagbasoke ati ilọsiwaju ipinlẹ ọhun.
Oni, Ọjọru, Wẹside ni Gomina Ṣeyi Makinde ṣe ileri naa niluu Ibadan, iyẹn nibi Hijrah 1444 to waye nileeṣẹ Gomina to wa lagbegbe Agodi.
Makinde ni ọdaran paraku ni gbogbo awọn ọta ipinlẹ Ọyọ, pẹlu ileri wi pe oun yoo gbogun ti wọn gidi, eyi ti yoo jẹ ki wọn kabamọ nla.
Lara awọn to wa nibẹ ni Oloye Bayọ Oyero, Sẹnetọ Mọnsurat Sumọnu, Okere t'ilu Ṣaki, Ọba Khalid Ọlabisi, Alaaji Hammẹd Raji (SAN) ati Ṣheik Taofeek Akewugbagold.
Siwaju si i lo jẹ ko di mimọ pe oun ti ṣiṣẹ takuntakun lori eto aabo ipinlẹ naa, ati pe gbogbo awọn ọta ipinlẹ ọhun ni ọdaran.
O loun yoo gbogun ti gbogbo wọn lai ni i wọju wọn tabi fẹẹ mọ iru eeyan ti wọn jẹ.
Bakan naa lo tẹsiwaju pe gbogbo awọn to fẹẹ ki ipinlẹ naa pin ni wọn yoo pofo, nitori pe awọn to n ṣe ẹsin mejeeji, iyẹn Kristẹẹni ati Musulumi lo wa ninu idile kọọkan.
No comments:
Post a Comment