Ile ẹjọ kotẹmilọrun to wa niluu Ibadan, ipinlẹ Ọyọ ti yẹyẹ olori ajijangbara ilẹ Yoruba, Oloye Sunday Adeyẹmọ, ti ọpọ awọn eeyan mọ si Sunday Igboho, lori ẹjọ to pe ijọba apapọ oeileede Naijiria.
Ọkan lara awọn eekan to n pe fun idasilẹ orilẹede Yoruba, Oloye Sunday Igboho ti fidi rẹmi niwaju ile ẹjọ kotẹmilọrun nilu Ibadan.
Adajọ gbe idajọ rẹ naa kalẹ lori ẹjọ kotẹmilọrun ti agbẹjọro agba ati ileeṣẹ agbofinro DSS pe tako idajọ ile ẹjọ giga ipinlẹ Ọyọ.
Ni ọdun to kọja ni ile ẹjọ giga ipinlẹ Oyo ni ki ijọba apapọ san ogun biliọnu Naira gẹgẹ bi owo itanran fun Igboho lori ẹtọ rẹ ti wọn tẹ mọlẹ.
Idajọ naa ni wọn gbe kalẹ lori ẹjọ naa lori Ayelujara, ti BBC Yoruba si tọpinpin rẹ.
Onidajọ Muslim Hassan to gbọ ẹjọ naa ṣalaye pe ogun biliọnu naira ti adajọ ile ẹjọ giga gbe kalẹ pe ki DSS ati ijọba apapọ san fun Igboho ko tọna.
Adajọ Hassan ni ko si alaye ti adajọ naa le e ṣe lori bi o ṣe ṣe akojọpọ adanu to ṣe Igboho lasiko ikọlu naa.
O ni bẹẹ ni ko si ẹri niwaju ile ẹjọ naa pe wọn ṣe odinwọn awọn dukia ti o bajẹ nile Sunday Igboho lasiko ikọlu naa.
Koko ẹjọ kotẹmilọrun mẹfa ni ileeṣẹ DSS ati ijọba apapọ gbe tọ ile ẹjọ kotẹmilọrun lọ.
Wọn si pe ẹjọ Kotẹmilọrun naa lẹyin idajọ ti ile ẹjọ giga ipinlẹ Ọyọ kan nilu Ibadan gbe kalẹ.
Ileejọ giga naa lo ni ijọba apapọ, amofin ati agbẹjọro agba Naijiria pẹlu ileeṣẹ alaabo DSS tẹ ẹtọ Sunday Igboho loju mọlẹ.
Adajọ naa ni eyi waye nipa kikọlu ile rẹ nitori bo ṣe n lewaju fun ipe fun idasilẹ orilẹede Oodua.
Ile ẹjọ kotẹmilọrun wa ni Adajọ Akintọla to gbọ ẹjọ naa nile ẹjọ giga
Ọyọ, ko laṣẹ lati gbọ ẹjọ ọhun labẹ igbẹjọ ẹsun kikọlu ẹtọ ọmọniyan.
Amọṣa, o ni pe ko sọrọ gidi kankan ninu ohun ti agbẹjọro fun DSS ati ijọba apapọ sọ pe ile ẹjọ giga ipinlẹ Ọyọ ko lẹtọ lati gbọ ẹjọ to ba kan ileesẹ ijọba apapọ.
O ni awijare wọn ko lẹsẹ nilẹ nitori naa oun wọgile ipẹjọ kotẹmilọrun lori koko yii.
Lara awọn abala idajọ ti ile ẹjọ giga ipinlẹ Ọyọ gbe kalẹ, leyi ti DSS ati ijọba apapọ tako nibi igbẹjọ ile ẹjọ kotẹmilọrun naa,
Awijare naa ni pe Sunday Igboho lẹtọ labẹ ofin ẹtọ ọmọniyan nilẹ Africa, iyẹn African Charter on idigenous rights, lati ko ẹgbẹ jọ fun idasilẹ orilẹede Yoruba tabi iyapa rẹ kuro labẹ orilẹede Naijiria.
Onidajọ Muslim Hassan sọ pe ijọba ati DSS sọ pẹlu ifidimulẹ pe Igboho n gbe awọn igbesẹ to n ti igi bọ oju abo lorilẹede Naijiria.
Bẹẹ ni wọn lo tun n gbe awọn ohun ija to n tọka si ifipa tu Naijiria ka.
O ni adajọ ile ẹjọ giga ipinlẹ Ọyọ to da Igboho lare labẹ ilakalẹ ofin African charter on indigenous rights, ko ku, idajọ naa si ku diẹ kaa to.
Adajọ Hassan ni ofin to gbe idajọ rẹ le lori ko tii ni ifidimulẹ lorilẹede Naijiria.
No comments:
Post a Comment