Awọn ara ati olugbe ipinlẹ Kwara ti pariwo sita wi pe Ọgbẹni Abdullateef Alagbonsi to jẹ alakoso ẹgbẹ kan ti wọn pe ni Elites Network for Sustainable Development (ENetSuD) lori bi ṣe lo gba obitibiti owo lọwọ oludije sipo gomina labẹ asia ẹgbẹ oṣelu Young Progressive Party, Malaamu Yakubu Gobir, to si na papa bora.
Wọn ni ṣe ni alakoso ENetSuD naa salọ si orileede Rwanda, to si lọ n na obitibiti owo ti ko din ni miliọnu mẹrindinlọgbọn ataabọ, N26.5m naira, eyi to gba lọwọ Malaamu Gobir lorukọ ẹgbẹ naa.
Owo naa ni wọn pe ni owo giranti (Grant), eyi ti wọn gba lọwọ ọkunrin.
A gbọ pe nnkan ti Malaamu Gobir gbe owo naa kalẹ fun kọ ni wọn fi n ṣe, ati pe ṣe ni Alagbọnsi gba owo naa, to si lọ fi n jaye familete ki n tutọ lorileede Rwanda to salọ.
Bẹ o ba gbagbe, laipẹ yii ni awọn alẹmode ipolongo idibo fun oludije sipo gomina naa, Gobir lu igboro ipinlẹ Kwara, eyi ti ẹgbẹ ENETSUD fi n polongo ibo fun un.
Ẹgbẹ ọhun nigba ti ọrọ naa jade sita, ni wọn l'awọn ko mọ ohunkohun nipa rẹ, ti wọn si n pe olori wọn lati wa ṣalaye bo 'se na owo to gba lọwọ Malaamu Gobir, nitori t'awọn ko mọ ohunkohun nipa rẹ.
Wọn ni ko wa a sọ ọ nita gbangba wi pe oun ko gba miliọnu mẹrindinlọgbọn ataabọ lọwọ Gobir, lẹyin ti awuyewuye ti kaakiri wi pe ẹgbẹ naa ti gba miliọnu mẹwaa naira.
No comments:
Post a Comment