Ọ ma ṣe o: Ọmọ ikoko ati eeyan marun-un padanu ẹmi wọn sinu ijamba mọtọ l'Ondo - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Wednesday, August 24, 2022

Ọ ma ṣe o: Ọmọ ikoko ati eeyan marun-un padanu ẹmi wọn sinu ijamba mọtọ l'Ondo


Ariwo ikunlẹ abiyamọ lo gba ẹnu awọn eeyan l'ọjọ Iṣẹgun, Tuside ọsẹ yii nigba ti ijamba kan to f'ẹmi eeyan mẹfa ọtọọtọ, eyi ti ọmọ ikoko kan naa wa laarin wọn ṣofo danu.
 
Ọpọ awọn eeyan la tun gbọ pe wọn farapa yannayanna ninu ijamba naa to waye lagbegbe Ajue, eyi to wa loju ọna marosẹ ilu Ondo si Ọrẹ.
 
A gbọ pẹ ọkunrin kan, obinrin mẹrin la gbọ pe wọn ba ijamba naa lọ, to si gba omije pupọ loju awọn to n kọja lọ, paapaa awọn tiṣẹlẹ naa ṣoju wọn.
 
Iroyin to tẹ wa lọwọ sọ pe tirela nla kan ti wọn pe ni tirọọki, eyi ti nọmba idanmọ rẹ jẹ MUS 321 YF, to n bọ lati ilu Ondo lo sọ ijanu rẹ nu lori ere, to si ṣe bẹẹ lọ doju kọ bọọsi Toyota Hiace, elero mejidinlogun ti nọmba idanimọ tiẹ jẹ RGB 487 XA.
 
Wọn ni ṣe ni tirela naa fo kuro loju ọna tiẹ, ko to lọ doju kọ bọọsi ọhun.
 
Awọn ẹlẹyinju aanu la gbọ pe wọn dsare sunmọ ibi ijamba naa lati doola ẹmi awọn eeyan, ko to di pe awọn oṣiṣẹ oju popona ti wọn ranṣẹ pe debẹ.

Nigba to n sọrọ, alakoso ẹkun Ọrẹ fun oṣiṣẹ aabo oju popona ti FRSC, Ọgbẹni Babafẹmi Alongẹ, to f'idi ijamba naa mulẹ sọ pe iwakuwa ẹni to wa tirela naa lo fa a to fi sọ ijanu rẹ nu, to si lọ fi koba awọn ẹni ẹlẹni.
 
O l'awọn ti ko awọn oku naa lọ mọṣuari, ti awọn to farapa si ti wa nibi ti wọn ti n gba itọju lọwọ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI