Ẹgbẹ awọn dọkita agbegbe lorieede yii, Nigerian Association of Resident Doctors, NARD, ti fi ẹbun awọọdu ti ko wọpọ ta gimina ipinlẹ Kwara, AbdulRahman AbdulRazaq lọrẹ, lori ipa to n ko lẹka eto ilera.
Wọn ni ko tii si ijọba ipinlẹ kankan lorileede Naijiria, to mu ọrọ eto ilera lokukudun to ijọba ipinlẹ Kwara ti AbdulRazaq jẹ gomina wọn.
Eyi lo fa a ti wọn fi wo o pe afi k'awọn da Gomina AbdulRahman AbdulRazaq lọla, lati fi mọ riri ipa to n ko lawujọ eto ilera, paapaa bi ẹmi ati dukia, eto ilera araalu fi jẹ ẹ logun.
Lakoko to n sọrọ ikini-kaabọ nibi eto ipade awọn alẹnulọrọ ẹgbẹ wọn, iyẹn Extraordinary National Executive Council Meeting, to waye ninu gbọngan ile itura ti Peace (Peace Hotel), niluu Ilọrin l'opin ọsẹ to kọja yii, Aarẹ ẹgbẹ naa, Dokita Dare Godiya Ishaya jẹ ko di mimọ pe bi wọn ṣe yan gomina AbdulRazaq kii ṣe nipa ojusaaju, bi ko ṣe nipa bo ṣe n gbe ẹka eto ilera larugẹ.
Nibẹ lo ti sọ pe iwuri jẹ fun ẹgbẹ naa lati ri i pe awọn oniṣegun oyinbo ti agbegbe ti bẹrẹ eto idanilẹkọọ l'ọsibitu ijọba to wa niluu Ilọrin.
O ni eto idanilẹkọọ naa ni yoo jẹ ki wọn ri awọn oniṣegun ilera to dantọ gbe dide, fun ijọba lati pin wọn si aaye to yẹ
Gomina AbdulRazaq nigba toun naa n fi idunnu rẹ han nibi eto ọhun, dupẹ gidigidi lọwọ awọn alakoso eto naa, to si ni ipenija lati tubọ tẹsiwaju iṣẹ rere rẹ ni awọọdu ọhun jẹ.
AbdulRazaq ti kọmiṣanna f'ọrọ eto ilera, Dokita Raji Razaq ṣoju fun, wa fikun ọrọ rẹ pe oun fi awọọdu naa sọri gbogbo awọn oṣiṣẹ eleto ilera ti wọn n fi ara ṣiṣẹ wọn fun idagbasoke ipinlẹ Kwara.
No comments:
Post a Comment