'Boya lẹ wa ok rara' - Lateef Adedimeji sọrọ buruku si ololufẹ rẹ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Sunday, August 14, 2022

'Boya lẹ wa ok rara' - Lateef Adedimeji sọrọ buruku si ololufẹ rẹ


Gbajugbaja oṣere tiata nni, Lateef Adedimeji ti sọrọ buruku si ọkan lara awọn ololufẹ rẹ lori ikanni ayelujara ti Instagiraamu l'opin ọsẹ to ṣẹṣẹ pari yii.

Lateef Adedimeji lo gbe fọto oun pẹlu iyawo rẹ, Bimpe Oyebade ti ọpọ awọn ololufẹ rẹ tun mọ si Mo-Bimpe sori ikanni ayelujara lọjọ Satide, ana.

A gbọ pe Lateef kọ ọ si abẹ fọto naa pe "Out with Iyawo Alhaji, looking regal", iyẹn ni pe mo jade pẹlu iyawo Alaaji, to dun un wo loju.

Bi Lateef ṣe gbe fọto ọhun sita l'awọn eeyan, paapaa awọn ololufẹ rẹ ti bẹrẹ sii kọ oriṣiriṣi ọrọ si abẹ fọto ọhun. B'awọn kan ṣe gbe oṣuba kare fawọn mejeeji, bẹẹ l'awọn miran n gbadura fun igbeyawo wọn.

Ọkan lara awọn to sọrọ sabẹ fọto naa to bi Lateef ninu lo sọ pe "Eyi dara pupọ, ṣugbọn Iyawo Alaaji ko nilo lati maa ṣi ara silẹ".

Eyi ni Lateef ri, to fi sare da a lohun pe "Bo ya lẹ wa ok rara".



No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI