Ìjọba Kwara san gbèse àjọ NBC tí ìjọba jẹ láti ọdún 2006 - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Thursday, August 25, 2022

Ìjọba Kwara san gbèse àjọ NBC tí ìjọba jẹ láti ọdún 2006


Ijọba ipinlẹ Kwara l'awọn ti san gbogbo gbese owo ajọ to n ṣabojuto eto igbohunsafẹfẹ lorileede yii, iyẹn National Broadcasting Commission ti ijọba wọn jẹ lati bi ọdun mẹrindinlogun sẹyin.

Laipẹ yii ni ajọ NBC gbe atẹjade kan sita nipa awọn ileeṣẹ igbohunsafẹfẹ ati amohunmaworan to jẹ gbese, ti wọn si kede pe awọn ti ti wọn pa.

Ipinlẹ Kwara ko gbẹyin ninu awọn ti ọrọ naa kan, ti a si gbọ pe miliọnu mejilelogun ataabọ (₦22.5m) naira lowo ti wọn jẹ lati ọdun 2006.

Bi iroyin ọhun ṣe tẹ Gomina AbdulRahman AbdulRazaq lọwọ, lo ti paṣẹ pe ki wọn tete lọ san gbese naa, lẹyin to bu ọwọ lu sisan an.

Kọmiṣanna f'ọrọ eto iroyin, Ọnarebu Ọlabọde George Towoju to fi iroyin ọhun sita sọ pe ṣaaju akoko yii ni ijọba ipinlẹ naa ti kọkọ san miliọnu mẹwaa naira ninu oṣu kẹsan, ọdun to kọja.

Ọnarebu Towoju lo jẹ ko di mimọ pe miliọnu mejilelọgbọn ataabọ (₦32.5m) naira ni apapọ owo naa tẹlẹ, to si l'awọn ti san gbogbo gbese naa lai ku ẹyọkan ṣoṣo.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI