Ija pari! AbdulRazaq ati Lai Mohammed pari ija oṣelu - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Wednesday, August 10, 2022

Ija pari! AbdulRazaq ati Lai Mohammed pari ija oṣelu


Orin 'ija d'opin, ogun si tan' l'awọn ara ati olugbe ipinlẹ Kwara, paapaa awọn ọmọlẹyin Gomina ipinlẹ naa, AbdulRahman AbdulRazaq ati minisita fọrọ eto iroyin ati aṣa lorileede yii, Alaaji Lai Mohammed n kọ lori b'awọn mejeeji ṣe pari ija oṣelu to wa laaarin wọn lati bi ọdun mẹta sẹyin.
 
Ki i ṣe iroyin tuntun mọ pe aarin Gomina AbdulRazaq ati Alaaji Lai Mohammed ko gun rege lati bi ọdun mẹta sẹyin, to si jẹ pe ko si nnkan to fa a ju ọrọ ipo oṣelu lọ, ṣugbọn ni bayii, a gbọ pe gbogbo aawọ naa ti d'ohun igbagbe patapata.

A gbọ pe lara awọn nnkan to dija silẹ nigba naa ni ẹni ti iṣakoso ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC nipinlẹ naa yoo wa lọwọ rẹ. Bi Gomina AbdulRazaq ṣe n sọ pe oun ni olori, bẹẹ ni Alaaji Lai Mohammed n sọ pe ko sẹni to le gba ipo olori lọwọ oun.
 
Wọn ni aawọ yii lo mu ki ẹgbẹ naa pin si meji, to fi jẹ pe bi Gomina AbdulRazaq ṣe wa lẹyin Abdullahi Samari gẹgẹ bi alaga ẹgbẹ APC nipinlẹ naa, ni Alaaji Alaaji Lai Mohammed wa lẹyin Bashiru Bolarinwa gẹgẹ bi alaga ẹgbẹ.

Lẹyin o rẹyin nibi ipade gbogboogbo ẹgbẹ naa to waye kọja lọ nipinlẹ Kwara, igun Gomina AbdulRazaq lo fa awọn oloye ẹgbẹ kalẹ, ti awọn igun yooku ko si rọwọ mu.
 
Nibẹ ni igun ti Gomina ti fa Omọọba Sunday Fagbemi kalẹ gẹgẹ bi alaga ẹgbẹ, eyi ti wọn lo f'opin si bi ẹgbẹ naa ṣe pin si meji.

Bo tilẹ jẹ pe a ko ti i le f'idi rẹ mulẹ titi di asiko ti a pari akojọpọ iroyin yii, sibẹ, a gbọ pe Alaaji Lai Mohammed ti paṣẹ pe ki gbogbo awọn ẹyin rẹ ṣagbatẹru AbdulRazaq lati pada s'ipo gomina lẹẹkeji, ati pe oun naa yoo wa lẹyin wọn digbi lati ri i pe ipo gomina ko bọ mọ ẹgbẹ APC lọwọ.

A gbọ pe bi wahala naa ṣe d'opin ki i ṣe bi AbduRazaq ṣe ṣagbatẹru bi awọn ọmọ ẹyin Lai Mohammed meji, Alaaji Bashir Bọlarinwa ṣe di alaga ileeṣẹ igbohunsafẹfẹ lapapọ, iyẹn National Broadcasting Commission (NBC), ati Alaaji Lukman Mustapha toun naa di alakoso ileeṣẹ Federal Mortgage Bank of Nigeria (FMBN).

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI