Diẹ lo ku ki tirela kan to ko ọpọlọpọ simẹnti jabọ lori afara nla to wa lopopona Eko si ilu Ibadan, ṣugbọn to jẹ pe ori lo ko awọn to wa ninu ẹ yọ lọwọ iku ojiji.
A gbọ pe ṣe ni ijanu tirela ọhun ja sọnu lori ere, ti ẹni to wa a ko si mọ ohun to le ṣe.
Lara awọn ti iṣẹlẹ naa ṣẹlẹ loju wọn sọ pe lati ma ba a paayan, lo mu ki awakọ rẹ fori sọ irin afara naa, to si ku diẹ ko jabọ silẹ.
Fun bi ọpọlọpọ wakati ni ijamba naa fi da sunkẹrẹ-fakẹrẹ ọkọ silẹ lopopona Eko si ilu Ibadan ọhun, ko to di pe awọn oṣiṣẹ eto aabo oju popo wa ọna abayọ sii.
No comments:
Post a Comment