Ẹ wo bi wọn ṣe fa irun ori akẹkọọ to ṣe irun tọọgi - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Wednesday, August 10, 2022

Ẹ wo bi wọn ṣe fa irun ori akẹkọọ to ṣe irun tọọgi


Ọrọ buruku toun tẹrin-in nigba ti awọn ọlọpaa Hisbah to wa n'ipinlẹ Kano deedee fa ori ọmọdekunrin akẹkọọ ile ẹkọ girama kan.

Ẹsun ti wọn ka si ọmọ naa l'ẹsẹ ni pe irun to lọ ṣe si ori rẹ tako ẹsin islamu ti wọn yan laayo.

Ile ẹkọ kan to wa ni ijọba ibilẹ Dawakin Tofa ni wọn sọ pe ọmọ ọhun n lọ, kods ti wọn sọ pe agbegbe naa lo n gbe.

Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, wọn ni irun ori ọmọ naa ko yatọ si ti tọọgi, eyi to mu ki wọn fa a dan kodoro.

Alẹ ana, Tuside ni awọn ọlọpaa Hisbah naa gbe e sori ayelukara wọn lati fi han gbogbo agbaye. 






No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI