Akinruyiwa tilu Owu Abẹokuta, Oloye Olumide Aderinokun ti rọ gbogbo awọn ọdọ jakejado orileede Naijiria, paapaa nipinlẹ Ogun lati maa lo ọgbọn ati imọ ti wọn ni lati fi mu idagbasoke ba agbegbe wọn.
Oloye Aderinokun, ẹni to tun jẹ oludije s'ipo ile igbimọ aṣofin agba orile-ede yii labẹ asia ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party, PDP lo sọrọ yii lakoko to b'awọn ọdọ yọ lori ayẹyẹ ọjọ wọn to n lọ lọwọ lonii, ọjọ Ẹti, Furaidee.
Gbogbo ọjọ kejila ninu oṣu kẹjọ, ọdọọdun ni ayajọ ọjọ awọn ọdọ lagbaye, eyi ti awọn ọdọ Naijiria naa ko gbẹyin.
Ninu atẹjade ikini rẹ, eyi ti akọwe ipolongo rẹ, Ọgbẹni Taye Taiwo fi sita lo ti ṣapejuwe awọn ọdọ gẹgẹ bi ẹbun nla pataki ti orileede ni, nitori pe lai si ọdọ, ko si nnkan to n jẹ itẹsiwaju.
O ni ilu tabi orileede ti ko ba ni ọdọ, tabi ko fi ti awọn ọdọ ṣe ṣetan lati parun lojiji, idi ree to fi ni ki awọn dide lati lọ awọn ọgbọn, imọ ti wọn ni nipa ṣayẹnsi lati fi mu idagbasoke ba agbegbe wọn.
Siwaju sii lo gb'awọn lamọran lati kopa ninu eto oṣelu to n bọ lọna yii, ki wọn si yan awọn aṣoju gidi ti yoo ṣoju wọn daadaa sipo.
O ni kii ṣe ahesọ tabi asọdun wipe ijọba APC ti dori eto ọrọ aje orileede yii, eyi to fi n sọ pe asiko to f'awọn ọdọ lati dide, ki wọn si fọwọsowọpọ lati fi ibo le wọn danu lọdun 2023.
No comments:
Post a Comment