Awọn adigunjale kọlu ile Saka, gbajumọ adẹrinpoṣonu - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Wednesday, August 10, 2022

Awọn adigunjale kọlu ile Saka, gbajumọ adẹrinpoṣonu


Titi di asiko ti a pari akojọpọ iroyin yii la gbọ pe ọkan gbajugbaja agba oṣere tiata nni, Hafiz Oyetoro ti ọpọ awọn eeyan mọ si Simply Saka lori b'awọn adigunjale ṣe kọlu ile rẹ to wa niluu Abẹokuta, ipinlẹ Ogun.
 
Nnkan bi agogo meji oru ọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii la gbọ pe awọn adigunjale naa kọlu ile Hafiz Oyetoro, ti wọn si n beere owo ti ko din ni ogun miliọnu naira.
 
A gbọ pe ṣe l'awọn adigunjale naa fẹẹ ji agba oṣere tiata ọhun gbe, ṣugbọn nigba ti wọn ri i pe gbajumọ oṣere ni, ati pe gbigbe rẹ yoo bu wọn lọwọ, lo jẹ ki wọn tun ero ọkan wọn pa.
 
Okan lara awọn ọrẹ timọtimọ ọkunrin naa to, Ọgbẹni Kayọde Ṣoaga tu aṣiri yii sita, sọ pe ṣe l'awọn adigunjale naa fẹẹ pa Saka danu, ṣugbọn to jẹ pe ori lo ko o yọ, iyẹn nigba ti ko ri owo ti wọn n beere lọwọ rẹ ko kalẹ.
 
Ṣoaga lo jẹ ka mọ pe ibọn nla loriṣiriṣi, ada, lẹbẹ at'awọn nnkan ija oloro ni wọn ko dani lọ loru ọjọ naa.
 
Oju ferese ni iroyin fi to wa leti pe awọn oniṣẹ buruku yii gba wọle sinu ile Saka.
 
Lẹyin idunnadura la gbọ pe wọn gba miliọnu mẹta naira lọwọ rẹ, to fi mọ awọn foonu rẹ, kaadi igbowo, kọmputa alagbeeka.
 
Siwaju si i la tun gbọ awọn oniṣẹ buruku yii gbe maṣiini ti wọn fi n gba owo, iyẹn POS dani, eyi ti wọn fi ko gbogbo owọ rẹ lọ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI