Àwa kò mọ ohunkóhun nípa ayédèrú nọ́mbà ọkọ̀ - APC Kwara pariwo síta - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Monday, August 1, 2022

Àwa kò mọ ohunkóhun nípa ayédèrú nọ́mbà ọkọ̀ - APC Kwara pariwo síta


Ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC nipinlẹ Kwara ti pariwo sita pe awọn ko mọ ohunkohun nipa nọmba ọkọ t'awọn eeyan n lo kaakiri igboro, to si ni ayederu ni wọn 

Wọn ni awọn nọmba ọkọ ti wọn kọ APC ati/tabi AA si ki i ṣe ojulowo nọmba idanimọ ọkọ to jade lati ọdọ wọn.

Ninu atẹjade ti ẹgbẹ naa fi sita lati ọwọ akọwe ipolongo, Alaaji Tajudeen Fọlaranmi Aro, l'Ọjọbọ, Tọside ọsẹ to kọja yii, APC sọ pe awọn to n lo fi n lu jibiti ni.

Siwaju sii ni APC jẹ ko di mimọ pe awọn ọmọ ẹgbẹ alatako lo wa nidii ayederu nọmba naa lati fi ṣi awọn araalu lọna, ati paapaa lati sọ wọn ni orukọ buruku.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI