Oludije s'ipo ile igbimọ aṣofin agba lorileede yii, lati ẹkun aarin gbungbun ipinlẹ Ogun, Oloye Olumide Aderinokun ti ṣe abẹwo ibanikẹkun lọ sile awọn obi ọmọdebinrin akẹkọọ ile ẹkọ giga gbogboniṣe ti Mọshood ABiọla, eyi to wa ni Ojere niluu Abẹokuta, Happiness Odeh ti wọn pa nipakupa l'ọsẹ to kọja yii.
Happiness Odeh l'awọn amookunṣeka pa danu lẹyin ti wọn f'ipa ba a laṣepọ tan lagbegbe Ipẹru Rẹmọ.
Ko pẹ ti ọmọbinrin naa ṣẹṣẹ gbegba oroke nibi idije Omidan Mapoly to waye lọjọ kẹta, oṣu kẹjọ ti a wa yii, ni wọn jiigbe, ko to di pe wọn dẹmi rẹ legbodo.
Nigba to n ṣabẹwo s'awọn obi ọmọ naa l'ọjọ Aje, Mọnde, ana, oludije labẹ asia ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party, PDP ṣapejuwe bi wọn ṣe pa Happiness gẹgẹ bi iwa ọdaju ati ainaanu.
Nibẹ lo ti ṣaleri iranlọwọ to pe ye f'awọn obi naa, to si rawọ ẹbẹ s'awọn alẹnulọrọ n'ipinlẹ Ogun lati rii daju pẹ wọn wa awọn to ṣiṣẹ buruku naa kan, ki wọn si rii daju pe wọn lọ lai jiya ẹṣẹ wọn.
No comments:
Post a Comment