Abẹokuta ni Ayọdele ti ji aṣọ ọlọpaa, ilu Ibadan lo ti fi n lu jibiti kaakiri - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Thursday, August 25, 2022

Abẹokuta ni Ayọdele ti ji aṣọ ọlọpaa, ilu Ibadan lo ti fi n lu jibiti kaakiri


Ọwọ ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ ti tẹ baale ile ẹni aadọta ọdun kan, Adebisi Ayọdele ti wọn lo n fi aṣọ ọlọpaa lu awọn araalu ni jibiti kaakiri igboro ilu Ibadan.

Ọjọ Aiku, Sannde to kọja yii la gbọ pe ọwọ tẹẹ ni agbegbe Aṣejire n'ijọba ibilẹ Ẹgbẹda niluu Ibadan nibi ti o ti mura ti o si n ṣiṣẹ ọlọpaa lọna aitọ.

Nọmba ọkọ Mitsubishi kan ti o fi n ṣiṣẹ gẹgẹ bi ẹṣọ aabo ni: ARP 34 AA.

Lasiko ti ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ n fi oju awọn ọdaran kan han ni olu ileeṣẹ ọlọpaa to wa ni agbegbe Ẹlẹyele nilu Ibadan ni ọrọ rẹ ti jade.

Kọmisọnna Ọlọpaa n'ipinlẹ Ọyọ, Adebọwale Williams ṣe alaye fun awọn akọroyin pe oṣiṣẹ ijọba to n bẹ ni ipele ikẹrinla ni Adebisi Ayọdele, ti o si n ṣiṣẹ gẹgẹ bii olukọ ile ẹkọ alakọbẹrẹ ni Ikereku-Idan, ilu Abẹokuta n'ipinlẹ Ogun.

Ileeṣẹ ọlọpaa fi idi ọrọ mulẹ wi pe Ayọdele ti fi oju han gẹgẹ bi ọṣiṣẹ ọlọpaa fun ọpọlọpọ ọdun ki ọwọ palaba rẹ to ṣegi.

Ninu ọrọ tiẹ, afurasi naa jẹwọ wi pe niṣẹ loun ji aṣọ ọlọpaa ati awọn eroja mii ti oun lo lọdọ aladugbo kan niluu Abẹokuta.

O ni, "Mo ji aṣọ ati awọn eroja ti o ku niluu Abẹokuta. Olukọ ile ẹkọ alakọbẹrẹ ni mi, mo si wa ni ipele ikẹrinla lẹnu iṣẹ ijọba.

"Bẹẹ sini mo fẹran iṣẹ ọlọpaa gan an de ibi wi pe gbogbo awọn ara adugbo wa ni mo ti sọ fun wi pe ọlọpaa ni mi."

Ayọdele fi kun ọrọ rẹ wi pe ni ọdun marun sẹyin ni oun ji aṣọ naa ko ti oun si ti n fi ṣiṣẹ, ṣugbọn oun ko fi aṣọ naa hu iwa ọdaran ri.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI