Ṣangba fọ! Ẹgbẹ oṣelu PDP ko ri owo ile san mọ ni Kwara, ni lanlọọdu ba fun wọn n'iwe lati kẹru jade - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Tuesday, July 5, 2022

Ṣangba fọ! Ẹgbẹ oṣelu PDP ko ri owo ile san mọ ni Kwara, ni lanlọọdu ba fun wọn n'iwe lati kẹru jade


Bi iroyin to tẹ AWIKONKO lọwọ laipẹ yii ba fi jẹ otitọ, a jẹ pe nnkan ti daru patapata fun ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party, PDP n'ipinlẹ Kwara.

Ohun ti a gbọ ni pe baba onile ti ẹgbẹ naa n lo fun olu ileeṣẹ ti fun wọn niwe lati ko jade, lori bi wọn ko ṣe ri owo ile naa san lati bi oṣu meloo kan sẹyin.

Ile ẹgbẹ naa to wa loju ọna Abdullahi Aguiye, GRA niluu Ilọrin la gbọ pe awọn igun mejeeji to n ja si iṣakoso rẹ ni wọn n da wahala owo ile naa silẹ.

A gbọ pe Aarẹ ile igbimọ aṣofin agba ana lorileede Naijiria, Bukọla Saraki lo n wọya ija pẹlu awọn oloye ẹgbẹ naa lori bi wọn ṣe fẹẹ san owo ọhun.

Bo tilẹ jẹ pe a ko ti i le f'idi rẹ mulẹ daadaa lakoko ti a ṣakojọpọ iroyin yii tan, wọn ni Bukọla Saraki lo n san owo naa tẹlẹ, ṣugbọn ti ko san ti ọdun yii nitori awọn idi pataki kan ti wọn ni ko ṣẹyin wahala to n ṣẹlẹ ninu ẹgbẹ naa.

Ninu ọrọ ti ọkan lara awọn ọmọ ẹgbẹ naa sọ, o ni "Latigba ti Saraki ko ti le ṣakoso ẹgbẹ naa mọ, ti ko si ri owo bo ṣe yẹ mọ ninu ẹgbẹ ni nnkan ti yi pada. Koda, mo le sọ pe latigba ti Bukọla Saraki ti kuro nipo gẹgẹ bi olori ile igbimọ aṣofin lo ti di pe oun pẹlu awọn agbaagba ẹgbẹ naa ti jọ n pin awọn owo to n wọle bakan naa.

"Laipẹ yii lo sọ pe oun ko ni san owo ile naa mọ, to si ni k'awọn agbaagba ẹgbẹ yooku lọ da owo laaarin ara wọn lati fi san an. Saraki lo si lo gbogbo agbara rẹ lati ri i pe ẹgbẹ naa duro ṣinṣin titi di oni ni Kwara."

A gbọ pe asiko perete ni baba onile naa fun wọn lati fi ko gbogbo ẹru wọn jade bi wọn ko ba ri owo ọhun san, ko si le gbe ile f'awọn to mọ iwulo rẹ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI