Ọba Abdulkadri Adelọdun, Alebioṣu keji, Ẹlẹsa tiluu Oke-Ode, to wa n’ijọba ibilẹ Ifẹlodun, ipinlẹ Kwara ti jade laye lẹni ọdun mọkalelọgọrin.
Kabiyesi naa la gbọ pe o waja lẹyin aisan rampẹ ti wọn loo niiṣe pẹlu ọjọ ogbo.
Akọwe ipolongo ti agbegbe Oke-Ode, Kunle Akọgun lo f’idi iroyin naa mulẹ niluu Ilọrin, l’Ọjọbọ ti i ṣe Tọside to kọja yii.
Akọgun sọ pe aarọ ọjọ naa ni kabiyesi mi eemi ikẹyin, to si ba awọn eeyan, paapaa awọn araalu lọkan jẹ gidi.
Ọdun 1985 la gbọ pe wọn de ade fun Ọba Abdulkadri Adelọdun gẹgẹ bi Ẹlẹsa tiluu Oke-Ode, ṣugbọn nitori ẹtaanu ati awọn wahala kan to ṣẹlẹ nigba naa, ile-ẹjọ giga rọ ọ l’oy l’ọdun 1992.
A gbọ pe loju ẹsẹ ni kabiyesi ti pe ẹjọ kotẹmilọrun, ti ile-ẹjọ kotẹmilọrun si da a lare, to si pada s’ori aleefa l’ọdun 1997, eyi to mu ki gbogbo awọn alatako rẹ gba kamu wi pe ko si nnkan t’awọn tun fẹẹ ṣe mọ.
Wọn ni asiko kabiyesi tu gbogbo araalu lara, nigba ti wọn ni bi eku ṣe n ke bi eku, naa l’awọn ẹyẹ n ke bi ẹyẹ, ti awọn ọmọ eeyan si n f’ọhun gẹgẹ bo ṣe yẹ.
Gomina ipinlẹ Kwara, AbdulRahman AbdulRazaq n’igba to n k’ẹdun iku Ọba naa, sọ pe ipa ti kabiyesi ko ninu eto idagbasoke agbegbe rẹ ko ṣe e fọwọ rọ ti sẹyin rara.
O ni awọn ọba ti wọn fi n gbadura fun ọba ni kabiyesi ọhun jẹ, to si ni gbogbo ilu ni yoo mọ pe eeyan nla lọ lawujọ wọn.
Gomina yii wa rọ gbogbo ọmọ ilu lati mu ọkan le, ki wọn si duro giiri, nigba to n gbadura fun wọn pe ki Ọlọrun tu gbogbo wọn lọkan.
No comments:
Post a Comment