Kwara wa lara awọn ipinlẹ diẹ to n san owo oṣu kikun fawọn oṣiṣẹ ijọba - AbdulRazaq - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Tuesday, July 19, 2022

Kwara wa lara awọn ipinlẹ diẹ to n san owo oṣu kikun fawọn oṣiṣẹ ijọba - AbdulRazaq


Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ti ipinlẹ Kwara ti jẹ ko di mimọ pe ipinlẹ naa wa lara awọn ipinlẹ perete ti wọn n san owo oṣu kikun fawọn oṣiṣẹ ijọba lorileede Naijiria.

AbdulRazaq ni, bi tilẹ jẹ pe owo to n wọle, ko to nnkan, iyẹn ni pe bi owo ti wọn n ri gba lati ọdọ ijọba apapọ (allocation) ti ṣe ja wa silẹ, sibẹ wọn ri i daju pe awọn oṣiṣẹ n gba owo oṣu wọn lẹkunrẹrẹ, lai yọ ninu ẹ.

Oni, ọjọ Iṣẹgun, Tusidee ni Gomina sọrọ naa, to si ni iṣakoso oun ti mu ní ojuṣe lati maa san ẹkunrẹrẹ owo oṣu fun gbogbo oṣiṣẹ patapata, to si n jẹ ko di mimọ pe igbayegbadun awọn oṣiṣẹ lo jẹ oun logun pupọ.

Siwaju si i lo ni owo ti wọn n gba lọdọ ijọba apapọ ko to nnkan, to si jẹ pe owo ti wọn n pa nipinlẹ naa ni wọn n ko mọ owo lati fi san owo oṣu, ati pe awọn tun n gbe owo kalẹ fawọn ijọba ibilẹ lati fi san owo oṣu lẹkunrẹrẹ.

Bẹẹ lo ni ati owo to n wọle lati Abuja, pẹlu eyi ti wọn n pa, ni wọn n lo lati fi ṣe gbogbo ohun yẹ ni ipinlẹ naa.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI