Oludije sipo ile igbimọ aṣofin agba lorileede yii, Oloye Olumide Aderinokun ti gbadura ifẹ, alaafia ati iṣọkan fun orileede Naijiria.
Nibi irun Yidi ti awọn ọmọlẹyin Anọbi, iyẹn awọn Musulumi lọ ki niluu Agbado, ijọba ibilẹ Ifọ, ipinlẹ Ogun ni Aderinokun ti gba adura naa.
Ṣe ni Oloye Aderinokun, ẹni to n jade du ipo naa lẹkun aarin gbungbun ipinlẹ Ogun, labẹ asia ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party, PDP gbarada, nigba ti awọn eeyan niluu Agbado jade lọpọ yanturu lati fi ẹmi imoore han.
Akinruyiwa tilu Owu, Abẹokuta naa lẹyin irun ti wọn ki gba adura idagbasoke fun orileede Naijiria, ati awọn aṣaaju lapapọ, to si tun lo anfaani naa lati gba awọn eeyan lamọran nipa gbigba ifẹ ati iṣọkan laayo.
Gbogbo awọn agbaagba ilu Agbado, to fi mọ awọn olori awọn Hausa lagbegbe naa ni wọn ko gbẹyin nibi irun Yidi ọhun.
Imaamu agba fun ilu Agbado, Imaamu Ahmad Ahmad dupẹ gidigidi lọwọ Oloye Aderinokun fun bo ṣe b'awọn tun mọṣalaṣi ilu Agbado kọ, pẹlu awọn nnkan amayedẹrun to tun fi sibẹ fun lilo araalu.
O wa rọ Aderinokun lati ma ṣe jinna si mọṣalaṣi Agbado, to si ni ko maa yọju si wọn loore koore.
Bi ojo naa ṣe rọ to, a gbọ pe awọn araalu jade lati fi ẹmi imoore wọn han si Oloye Aderinokun, fun ipa rere idagbasoke rẹ laaarin gbungbun ipinlẹ Ogun.
No comments:
Post a Comment