Iléyá! Adérìnókùn fẹ́ẹ́ fi ẹran àgbò ọ̀ọ́dúnrún tọrẹ f'áwọn Mùsùlùmí - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Tuesday, July 5, 2022

Iléyá! Adérìnókùn fẹ́ẹ́ fi ẹran àgbò ọ̀ọ́dúnrún tọrẹ f'áwọn Mùsùlùmí


Lasiko ti a pari akojọpọ iroyin yii, ko din ni ẹran agbo ọọdunrun ti oludije s'ipo ile igbimọ aṣofin agba orile-ede Naijiria lati ẹkun aarin gbungbun ipinlẹ Ogun, Oloye Olumide Aderinokun ti ko kalẹ lati fi tọrẹ f'áwọn musulumi, ki wọn le ri i fi ṣe ọdun.

Yatọ si eyi, a gbọ pe ounjẹ ti ko din ni ẹgbẹrun meji tun ti wa nilẹ ti Aderinokun tun fẹẹ fi tọrẹ lakoko ọdun Ileya to wọle yii.

Bẹ o ba gbagbe, opin ọsẹ ti a wa yii, iyẹn ọjọ Abamẹta, Satide ni gbogbo awọn musulumi kaakiri agbaye n ṣe ayẹyẹ odun Ileya wọn, to si pọn dandan lati pa ẹran agbo, iyẹn fun awọn to ba ni agbara rẹ.

Aderinokun to n dije labẹ asia ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party, PDP la gbọ pe o fẹẹ pin awọn agbo naa kaakiri ẹkun ati ijọba ibilẹ to wa labẹ aarin gbungbun ipinlẹ Ogun bi i Ifọ, Ọbafẹmi Owode, Abẹokuta South/North, Ọdẹda, to fi mọ Ewekoro.

Gẹgẹ bi olobo to ta si wa leti, a gbọ pe awọn ounjẹ tutu, ti awọn eeyan yoo lọ se nile wọn fun ọdun ni Akinruyiwa tilu Owu naa fẹẹ pin fun idile ẹgbẹrun meji.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI