Iléyá: AbdulRazaq kí gbogbo mùsùlùmí jákèjádò - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Saturday, July 9, 2022

Iléyá: AbdulRazaq kí gbogbo mùsùlùmí jákèjádò


Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ti ipinlẹ Kwara ti ba awọn musulumi kaakiri agbaye, paapaa nipinlẹ naa yọ ayọ ayẹyẹ ọdun Ileya to wọle yii.

Bakan naa lo tun ki gbogbo awọn to lọ gun oke Arafa niluu Mẹka ti Mẹdina pẹlu awọn lọ ṣe Eid-el-Adha, to si ni mejeeji yii jẹ ohun t'awọn onigbagbo ninu ẹsin n ṣe lati fi wa ojurere Ọlọhun, Allah.

O rọ gbogbo awọn to lọ ṣe Hajj lati mu awọn ẹkọ ti wọn ri kọ nibẹ lo bi wọn ṣe n pada si orileede Naijiria, paapaa ipinlẹ Kwara, fun idagbasoke, ifẹ ati iṣọkan.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI