Ijọba ipinlẹ Ogun tun ti kede ọjọ Ẹti, Furaidee, ọni gẹgẹ bi ọjọ isinmi f'awọn oṣiṣẹ kaakiri ipinlẹ naa, pẹlu erongba lati fun wọn lanfaani gbigba kaadi idibo alalopẹ, PVC wọn.
Eyi ni yoo jẹ igbakeji ti ijọba ipinlẹ naa yoo kede isinmi f'awọn oṣiṣẹ ninu ọsẹ ti a wa yii, lori gbigba kaadi idibo alalopẹ.
Ọjọ Iṣẹgun, Tusidee ni ijọba ti ṣaaju fi silẹ fawọn oṣiṣẹ, ṣugbọn ti iroyin pada fi idi rẹ mulẹ pe asiko ọhun kere pupọ.
Ninu atẹjade ti akọwe iroyin gomina, Kunle Ṣomọrin fi sita l'Ọjọbọ, Tọside ọsẹ yii, o ni ijọba ko fẹẹ yọ ẹnikẹni silẹ lati gba kaadi idibo alalopẹ naa, ki wọn le ni anfaani lati dibo lọdun to n bọ.
No comments:
Post a Comment