Igbesẹ ti bẹrẹ lati ko ile-ilẹ Itakudima kuro - Ijọba - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Thursday, July 7, 2022

Igbesẹ ti bẹrẹ lati ko ile-ilẹ Itakudima kuro - Ijọba


Ijọba ipinlẹ Kwara ti sọ pe igbesẹ ti bẹrẹ lati pa agbegbe kan t'awọn araalu sọ di ile-ilẹ rẹ, nitori pe ibi ti ko bojumu to ni wọn sọ di ile-ilẹ apapandodo lojiji.
 
Ile-Ilẹ Itakudima to wa niluu Ilọrin, ipinlẹ naa ni ijọba sọ pe ohun fẹẹ palẹmọ kuro nibẹ, lojuna lati gba imọtoto ati alaafia laaye.

Gẹgẹ bi Kọmiṣanna fọrọ eto ayika ati agbegbe, Ọnarebu Rẹmilẹkun Banigbe ṣe sọ lasiko to ṣabẹwo si ibi ile-ilẹ naa to wa ni Itakudima, agbegbe Zuban, ijọba ibilẹ Guusu Ilọrin, o ni bi wọn ṣe sọ ibẹ di ibi ti wọn n da idọti si ko bojumu to.

Banigbe sọ pe abẹwo toun ṣe sibẹ ko ṣẹyin bi ijọba ṣe n gbero lati pa gbogbo awọn agbegbe ti wọn sọ di ile-ilẹ rẹ kuro, ki alaafia si jọba laaarin ilu, ati pe wọn yoo wa nnkan gidi ṣe sibẹ, dipo ile-ilẹ.
 
Ninu ọrọ tirẹ, akọwe agba lẹka ileeṣẹto n ri sọrọ ayika ati agbegbe, Arabinrin Dupẹ Adekẹyẹ, o jẹ ko di mimọ pe ewu nla ni ile-ilẹ naa n jẹ si ilera gbogbo awọn to n gbe ni ayika ati agbegbe naa.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI