Ṣẹnkẹn bayii ni inu awọn olugbe ipinlẹ Ogun, paapaa awọn to n gbe lagbegbe aarin gbungbun ipinlẹ naa n dun, nigba ti oludije sipo ile igbimọ aṣofin agba lorileede yii, Oloye Olumide Aderinokun pin ẹbun ọdun fun wọn bi ayẹyẹ ọdun Ileya ṣe wọle de yii.
Ẹran agbo ti ko din ni ọọdunrun (300), ati oriṣiriṣi ounjẹ fun awọn eeyan to le ni ẹgbẹrun meji la gbọ pe Aderinokun to n dije labẹ asia ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party, PDP pin fawọn araalu, paapaa awọn musulumi.
A gbọ pe ko si ojusaaju ninu bi wọn ṣe pin awọn ẹbun naa kaakiri ijọba ibilẹ mẹfẹẹfa to wa ni aarin gbungbun ipinlẹ Ogun lonii, Ọjọbọ, Tọside.
Lara awọn to jẹ anfaani yii la gbọ pe wọn wa lati ijọba ibilẹ Guusu ati Ariwa Abẹokuta, Ewekoro, Ifọ, Ọbafẹmi-Owode ati Ọdẹda.
Nigba to n sọ idi pataki to fi pin ẹbun ọdun naa, Aderinokun, ẹni to tun jẹ Akinruyiwa tilu Owu l'Abẹokuta sọ pe bi eto ọrọ aje orileede Naijiria ṣe dẹnukọlẹ, to si fa iṣoro to pọ fun awọn araalu lo jẹ koun ṣe iranlọwọ bẹẹ fun wọn.
O ni ọpọ awọn idile lo wa, to jẹ pe wọn ko ni nnkan ti wọn maa fi ṣe ọdun Ileya, eyi to ni ko bojumu to, to si ni lara iṣẹ ti Adẹdaa fi ran oun ni aanu ṣiṣe.
Nibẹ lo ti jẹ ko di mimọ pe ọdun 2020 loun ti bẹrẹ pinpin ounjẹ ọdun fawọn araalu, pẹlu ileri wi pe oun ko ni dawọ rẹ duro.
Gbogbo awọn to jẹ anfaani yii patapata ni wọn n ṣe adura fun ọkunrin naa, ti wọn si ni awọn ko le gbagbe rẹ titi lai, ati pe iru awọn adari t'awọn n fẹ lorileede Naijiria ni Olumide Aderinokun jẹ.
No comments:
Post a Comment