Kani kii ṣe ori to ko gendekunrin kan ti wọn sọ pe afurasi ọmọ Yahoo-Yahoo yọ ni, boya ohun ti a n kọ yii kọ lao ba maa kọ, lori bi wọn ṣe sọ pe ere asapajude fẹẹ ran an lọ s'ọrun aremabọ.
Ori afara nla ti Itoku la gbọ pe ọmọkùnrin naa ti kagbako ijamba ọkọ, koda ti wọn sọ pe diẹ lo ku ko jabọ silẹ lati ori afara ọhun.
Awọn ti iṣẹlẹ naa ṣoju wọn sọ pe ori ere asapajude lo wa pẹlu mọto Toyota Camry (Muscle) rẹ, to jẹ alawọ pupa, wọn ni igba ti yoo fi de agbegbe kan lori afara naa, ni ijanu rẹ ko fẹẹ mu, to si gun irin ti wọn fi dena ki awọn eeyan ma le jabọ silẹ.
Irin naa lo gbe mọto ọhun duro.
No comments:
Post a Comment