Ẹgbẹ akẹkọọjade ile-ẹkọ girama ti Rẹmọ fẹẹ ṣi ile ẹgbẹ tuntun lorukọ Akarigbo t'ilẹ Rẹmọ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Tuesday, July 12, 2022

Ẹgbẹ akẹkọọjade ile-ẹkọ girama ti Rẹmọ fẹẹ ṣi ile ẹgbẹ tuntun lorukọ Akarigbo t'ilẹ Rẹmọ


Gbogbo eto lo ti pari patapata fun ẹgbẹ awọn akẹkọọjade ti ile-ẹkọ Rẹmọ, iyẹn Remo Secondary School Old Students' Association (RSSOSA) lati ṣe ifilọlẹ ile egbẹ tuntun ti wọn sọ lorukọ Akarigbo t'ilẹ Rẹmọ, Ọba Babatunde Ajayi.
 
Ọjọ kẹẹdogun, oṣu keje, ọdun ti a wa yii la gbọ pe eto naa fẹẹ waye ninu ọgba ile-ẹkọ naa to wa niluu Ṣagamu, ipinlẹ Ogun.
 
Iroyin to tẹ AWIKONKO lọwọ nipa eto ọhun sọ pe wọn tun fẹẹ lo anfaani rẹ lati ṣe idanilẹkọọ awọn aṣaaju, iyẹn Leadership Workshop f'awọn akẹkọọjade ara wọn, ni oriṣiriṣi ẹka iṣẹ ti wọn yan laayo.
 
Bo tilẹ jẹ pe ileẹgbẹ naa ti wa tẹlẹ, ṣugbọn ṣe ni wọn ṣe atunkọ rẹ lọna igbalode, ti wọn si ko awọn ohun elo amayederun sibẹ fun igbadun ati ilọsiwaju awọn ọmọ ẹgbẹ.
 
Wọn ni ita ile-ẹgbẹ naa ṣe dun un wo, naa ni ayika ati agbegbe rẹ fanimọra, ti inu rẹ si dabi ilẹ aarẹ ti ilu Oyinbo, iyẹn nibi to rẹwa de.
 
Lara awọn alejo ti wọn n reti l'ọjọ naa ni Kọmiṣanna f'eto ẹkọ, Ọjọgbọn Abayọmi Arigbabu; Ọjọgbọn Adeleke Oduwaiye; Ọtunba Tunji Ṣolarin Lawal, at'awọn miran.
 
Yatọ si pe wọn sọ orukọ ile-ẹgbẹ ọhun l'orukọ Ọba Babatunde Ajayi, wọn ni Kabiyesi ni Ọba alaye ọjọ naa, ti gbogbo nnkan yoo si lọ bo ṣe yẹ, pẹlu eto aabo to peye.
 
Bakan naa la gbọ pe kaadi ipe pelebe ti wọn ti ṣeto silẹ ni awọn alejo yoo fi wọle l'ọjọ naa, to si jẹ pe wọn yoo tun ṣe fọnran rẹ bi nnkan ṣe n lọ l'ọjọ naa, t'awọn jakejado agbaye yoo si maa wo o lori ikanni ayelujara.
 
Gbogbo awọn to ti kẹkọọjade nile-ẹkọ yii ni wọn n reti l'ọjọ naa, lai ni i ṣe pẹlu ọdun tabi igba ti wọn jade.






No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI