Gbogbo awọn ara ati olugbe agbegbe Ṣajẹ, Ẹlẹga, Arinlẹsẹ, Itoko ati agbegbe rẹ to wa niluu Abẹokuta, ipinlẹ Ogun ni wọn ti pariwo sita fun iranlọwọ lori aisi ina mọnamọna.
Wọn lo ti le l'oṣu meji t'awọn ti wa ninu okunkun biribiri, bo tilẹ jẹ pe wọn n san owo ina lasiko to yẹ.
Gbogbo agbegbe yii ni wọn wa labẹ ijọba ibilẹ Abẹokuta North.
Wọn ni aisi ina mọnamọna latigba naa ti ṣakoba pupọ fun eto ọrọ aje awọn agbegbe ọhun, koda, ti wọn sọ pe eto ọrọ aje wọn ti dẹnukọlẹ patapata.
Ọkan lara awọn olugbe agbegbe yii, Arabinrin Afọlaṣade to ba oniroyin sọrọ lori iṣoro ti wọn n koju nipa aisi ina mọnamọna jẹ ko di mimọ pe lati oṣu karun-un, ọdun yii l'awọn ti kofiri ina gbẹyin.
Afọlaṣade sọ pe bi wọn ba kofiri ina lagbegbe ọhun, a jẹ pe ina ẹrọ amunawa ti jẹnẹretọ ni, nitori pe awọn oṣiṣẹ ileeṣẹ mọnamọna ko fun wọn ni ina.
O tẹsiwaju pe gbogbo owo l'awọn ti fi ra epo bẹntiroolu tan, pẹlu bi ko tun ṣe si epo rọbii naa nigboro, ati bi bi wọn tun ṣe gbe owo le e.
Ọkan lara awọn oṣiṣẹ ileepo to wa nitosi agbegbe yii sọ pe o ti mọ awọn eeyan lara lati maa tan jénẹretọ, nigba ti ko si ina mọnamọna mọ.
Ninu ọrọ rẹ, ọkunrin naa ni ki i ṣe nnkan tuntun mọ pe awọn eeyan n tan jẹnẹretọ, nitori pe ohun to ti mọ wọn lara ni, ati pe bi ọrọ orileede yii ṣe gba niyẹn.
Ọpọ awọn to n taja lagbegbe naa ni wọn kọminu lori aisi ina mọnamọna, ti wọn si l'awọn ti paara ọfiisi ileeṣẹ mọnamọna, ṣugbọn ti wọn ko ri nnkan ṣe si i.
Wọn wa rawọ ẹbẹ s'ijọba orileede yii, paapaa awọn ti ọrọ kan lati ṣe ohun to tọ, ati ohun to yẹ lasiko, ki wọn le maa jẹ anfaani eto ijọba awaarawa.
No comments:
Post a Comment