Ẹgbẹ obi awọn akẹkọọ, iyẹn Parents Association of Students on Exchange Programme (PASEP), nile ẹkọ ijọba, Government Secondary School (GSS), eyi to wa niluu Ilọrin, ipinlẹ Kwara ti gbe oriyin fun Gomina AbdulRahman AbdulRazaq lori bo ṣe n san awọn owo iranwọ fawọn ọmọ wọn.
Ninu atẹjade ti alaga wọn, Ahmẹd Funsho, ati akọwe wọn, Shehu Gidado jọ bu ọwọ lu, wọn ni ijọba ipinlẹ naa fun wọn ni koriya nipa sisan owo mọto wọn latigba ti iṣakoso naa ti wa lori aga, eyi ti wọn lo n jẹ k'awọn akẹkọọ naa maa kẹkọọ lai ni idiwọ.
Wọn ni owo ti ko din ni miliọnu mẹẹdogun naira ni iṣakoso to kọja jẹ wọn, ki wọn to kogba wọle, to si jẹ pe gbogbo bi wọn ṣe n beere ni wọn ko ri ti wọn ro rara, ṣugbọn ti wọn ni Gomina AbdulRazaq ti jẹ ki wọn mọ pe oun nifẹẹ akẹkọọ.
Owo iranwọ yii la gbọ pe gbogbo awọn akẹkọọ ti wọn n kẹkọọ l'awọn ilu miran nilẹ Hausa orileede yii n jẹ anfaani rẹ.
Nibẹ ni wọn ti wa rawọ ẹbẹ s ijọba lati fun wọn ni bọọsi ti yoo jẹ ki iṣẹ wọn rọrun pupọ, pẹlu ileri wi pe awọn yoo ṣe iranwọ fun ipolongo saa keji.
No comments:
Post a Comment