Ọwọ ileeṣẹ aabo ara-ẹni laabo ilu, ti a mọ si Sifu Difẹnsi ti tẹ awọn gendekunrin mẹta kan, Lawal Ibrahim, ọmọ ọdun marundinlọgbọn; Mohammed Issa, ọmọ ọdun mọkandinlogun; ati Ibrahim Ahmẹd, toun jẹ ọmọ ọgun ọdun.
Abule Woro to wa n'ijọba ibilẹ Kaiama, ipinlẹ Kwara la gbọ pe ọwọ ti tẹ awọn mẹtẹẹta.
Wọn ni ṣe l'awọn mẹtẹẹta lọ d'igun ba obinrin alaboyun naa ati ọkọ rẹ nile, ti wọn fi ja wọn lole, ko to di pe wọn f'ipa ba obinrin naa lasẹpọ pẹlu oyun oṣu meje ninu.
Ọjọ keje, oṣu keje ti a wa yii la gbọ pe iṣẹlẹ naa waye, ti wọn si loju ẹsẹ ni wọn ti lọ f'ọrọ ọhun to awọn oṣiṣẹ Sifu Difẹnsi leti, ko to di pe wọn bẹrẹ iṣẹ iwadii wọn.
Alukoro ileeṣẹ naa, Ayẹni Ọlasunkanmi to f'idi iṣẹ yii mulẹ sọ pe ibi ti ọkan lara wọn, iyẹn Ibrahim ti n gbero lati ta awọn nnkan ti wọn jigbe lọwọ palaba rẹ ti segi.
O ni jijẹwọ ti Ibrahim jẹwọ lo mu ki wọn beere awọn yooku rẹ, to si ṣatọna b'ọwọ ṣe tẹ wọn lẹyọkọọkan.
Ayẹni wa fi ye wa pe awọn eeyan naa yoo f'oju ba ile-ẹjọ laipẹ.
No comments:
Post a Comment