Ko ti i ju wakati mẹrinlelogun ti awọn agbebọn to n f'ojoojumọ da orileede Naijiria kede sita wi pe awọn fẹẹ ji Aarẹ orileede yii, Muhammadu Buhari gbe, ni wọn kọlu ọkọ akọwọrin rẹ.
Lara awọn ọkọ akọwọrin Aarẹ Buhari ti awọn ẹṣọ aabo rẹ wa nibẹ l'awọn agbebọn yii kọlu, pẹlu erongba lati jẹ ki wọn mọ bi agbara wọn ṣe to.
Yatọ si aarẹ ti awọn agbebọn wọnyi sọ pe awọn fẹẹ jigbe, wọn l'awọn tun fẹẹ ji gomina ipinlẹ Kaduna, Nasir El-Rufai naa gbe pẹlu.
Awọn ọmọ ogun mẹta la gbọ pe wọn farapa yannayanna nibi ikọlu ọhun to waye niluu Abuja, to si ko ibẹrubojo b'awọn araalu.
Iroyin to tẹ wa lọwọ sọ pe ile-ẹkọ ofin orileede yii, iyẹn Nigerian Law School to wa lagbegbe Bwari l'awọn agbebọn ọhun n lọ ko to di pe wọn ṣalapade ikọ akọwọrin aarẹ naa.
Wọn ni awọn agbebọn naa ti rọgba yi ilu Abuja ka, pẹlu erongba lati ji awọn akẹkọọ ile-ẹkọ ofin naa gbe, gẹgẹ bi wọn ṣe lasiko iṣakoso Aarẹ Goodluck Jonathan.
No comments:
Post a Comment