Mọlẹbi oludije s'ipo ile igbimọ aṣofin agba orileede yii labẹ asia ẹgbẹ oṣelu Social Democratic Party, SPD lati ẹkun aarin gbungbun ipinlẹ Kwara, Ridwan Apaokagi ti fi idaniloju wọn han wi pe awọn yoo ṣatilẹyin fun ipolongo idibo saa keji fun Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ninu idibo ọdun 2023 to n bọ lọna.
Nibi abẹwo ibanikẹnidun ti Gomina AbdulRazaq ṣe lọ sile mọlẹbi naa, lori iku Alaaja Fatimat Baidowu Apaokagi to jẹ gẹgẹ bi ẹni to ku fun oludije aṣofin agba naa, Ridwan Apaokagi ni mama.
Gomina AbdulRazaq sọ nibẹ pe oṣelu toun n ṣe n'ipinlẹ naa ki i ṣe ti ẹtaanu, bi ko ṣe pe ifẹ ati alaafia nikan lo le mu ki ilu tẹsiwaju.
Oloogbe naa, Alaaja Fatimat Baidowu Apaokagi, ni iyawo akọkọ ti Oloogbe Alaaji Khidru Sallahudeen Apaokagi, ẹni to ti figba kan ri jẹ Grand Mufty keji niluu Ilorin.
Nibẹ ni wọn ti dupẹ gidigidi lọwọ AbdulRazaq lori bo ṣe fun ọkan lara awọn ọmọ wọn, Faosiyah Apaokagi ni angfaani eto ẹkọ ọfẹ titi ti yoo fi jade ile-ẹkọ giga.
Faosiyah Apaokagi lo gbegba oroke nibi idije kan to waye laipẹ yii niluu Eko, to si jẹ ẹbun to to idaji miliọnu naira lọwọ AbdulRazaq.
Wọn wa l'awọn ṣetan lati ṣatilẹyin fun ipada sipo lẹẹkeji Gomina AbdulRazaq lọdun 2023.
No comments:
Post a Comment