O ma ṣe o: Eeyan marun-un ku s'inu ijamba ọkọ loju ọna Abẹokuta - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Sunday, June 26, 2022

O ma ṣe o: Eeyan marun-un ku s'inu ijamba ọkọ loju ọna Abẹokuta


Ariwo ikunlẹ abiyamọ lo gba ẹnu awọn ara agbegbe Day Waterman to wa loju ọna marosẹ ilu Abẹokuta siluu Ṣagamu, ipinlẹ Ogun l'ọjọ Abamẹta, Satide to kọja yii, nibi ti ijamba ọkọ ti fi ẹmi eeyan ti ko din ni marun-un ṣofo danu.

Inu agbara ẹjẹ la gbọ pe awọn maraarun ku si, nitori bi mọto wọn ṣe run womuwomu, to si jẹ pe ori lo ko awọn mẹta yọ, bo tilẹ jẹ pe ṣe ni wọn farapa yannayanna.
 
Gẹgẹ bi agbẹnusọ fun ẹṣọ oju popona n'ipinlẹ Ogun, iyẹn TRACE, Ọgbẹni Babatunde Akinbiyi ṣe ṣalaye f'AWIKONKO, o ni mọtọ ayọkẹlẹ Mazda kan ti nọmba idanimọ rẹ jẹ KRD 975 HJ lo kagbako pẹlu mọto akẹru miran ti nọmba idanimọ tiẹ jẹ T-14214 LA, to si ṣe bẹẹ gb'ẹmi awọn eeyan wọnyii.

Akinbiyi jẹ ko ye wa pe nnkan bii agogo mẹrin irọlẹ ku iṣẹju mẹẹẹdogun niṣẹlẹ naa waye l'ọjọ Satide, to si l'awọn oṣiṣẹ wọn ni wọn sare debẹ lati ṣe iranwọ, gẹgẹ bi iṣẹ wọn.

O ni awakọ to wa ọkọ akẹru ọhun lo n wa mọto rẹ lọna aitọ, ko to ṣeeṣi lọ ya gba mọto ayọkẹlẹ Mazda naa, eyi to ṣe akoba f'awọn mẹjọ.


Siwaju si i lo jẹ ko ye wa pe loju ẹsẹ ti ijamba yii ti ṣẹlẹ ni awakọ akẹru naa ti juba ehoro, ti ko si sẹni to le sọ pato ibi to wọlẹ si i.

Wọn ti gbe oku awon to ṣalaisi lọ silee igbokusi lọsibitu ijọba to wa n’Ijaye, l’Abẹokuta, ati t’Idera to wa ni Ṣagamu.

Ajọ TRACE ba ẹbi awọn to padanu emi wọn kẹdun, bẹẹ ni wọn tun kilọ fawọn awakọ, paapaa awọn onitirela atọkọ akẹru, pe kí wọn maa tẹle ofin irinna, ki wọn yee ṣe bíi pe awọn nikan lọna wa fun, ki wọn yee dunkooko mawọn ọkọ to kere si wọn.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI