Mo ṣetan lati b'awọn oṣiṣẹ to da iṣẹ silẹ ṣe ipade alaafia - Dapọ Abiọdun - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Tuesday, June 28, 2022

Mo ṣetan lati b'awọn oṣiṣẹ to da iṣẹ silẹ ṣe ipade alaafia - Dapọ Abiọdun


Gomina Dapọ Abiọdun ti ipinlẹ Ogun loun ti ṣetan lati jokoo papọ ṣe ipade pọ pẹlu ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ ipinlẹ naa to da iṣẹ silẹ lojiji, ki wọn le jọ sọ asọyepọ.

Lonii, Ọjọ Iṣẹgun, Tusidee ni agbarijọ ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ kaakiri ipinlẹ ọhun bẹrẹ iyanṣẹlodi, lẹyin ti ipade ti wọn ṣe lọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii, nibi ti wọn l’awọn ko ti i le sọ igba ati akoko ti wọn yoo pada s’ẹnu iṣẹ wọn.
 
Ọla, Ọjọru ti i ṣe Wẹside ni gomina sọ pe oun yoo ṣe ipade papọ pẹlu awọn oṣiṣẹ ọhun, to si loun ṣetan lati tẹti gbọ gbogbo ohun ti wọn n beere fun.

Ninu atẹjade ti kọmiṣanna f’eto iroyin n’ipinlẹ Ogun, Alaaji Waheed Oduṣile fi sita lalẹ oni (Tusidee) lo ti sọ pe gomina fẹẹ b’awọn oṣiṣẹ naa ṣe ipade papọ gẹgẹ bi ipinnu rẹ lati ri sọrọ igbayegbadun wọn.

“Mo ti mu gẹgẹ bi ojuṣe lati jẹ ki ọrọ awọn oṣiṣẹ n’ipnlẹ Ogun jẹ mi logun, ti mo si ṣetan lati maa fi si ojuṣe. Ọrẹ awọn oṣiṣẹ ni iṣakoso yii jẹ, ti yoo si maa ri bẹẹ lọ labẹ iṣakoso mi.”.

“Ọkan lara awọn ojuṣe mi ti mo ṣe lọjọ akọkọ ti mo de ipo gomina l’ọgbọn ọjọ, oṣu karun-un, ọdun 2019 ni lati bu ọwọ lu owo oṣu gbogbo awọn oṣiṣẹ patapata, eyi ti iṣakoso to kọja ko tete san nigba naa.

“Mo tun ṣe ileri wi pe gbogbo awọn oṣiṣẹ ni wọn maa gba owo oṣu wọn ko to o to tabi ni ipari oṣu. A si ti n ṣe bẹẹ latigba ti a ti bẹrẹ iṣẹ.

“Koda, pẹlu bi ko ṣe si owo nilẹ to, ti bukata si n yọju ati iyanṣẹlodi yii, a tun ṣi san owo oṣu. O da mi loju pe laaarin wakati mẹrinlelogun si asiko yii, wọn maa bẹrẹ si i ri owo oṣu wọn fun ti oṣu kẹfa yii. A jẹ ọkan lara awọn ipinlẹ lorileede yii ti wọn ko jẹ owo oṣu, ti a si n san an lasiko to yẹ”, Gomina Dapọ Abiọdun.

Siwaju si i ni Gomina Abiọdun tun sọ pe ohunkohun ti awọn oṣiṣẹ le maa beere fun bayii, loun yoo tẹti gbọ, ti wọn yoo si wa iyanju si, ati pe ọpọ ohun t’awọn oṣiṣẹ naa n beere fun lo jẹ labẹ iṣakoso to kọja lo ti wa, ṣugbọn gẹgẹ bi ijọba to mọ ojuṣe rẹ, ẹyọkọọkan ti wọn n yọsẹ lawo lohun n ṣe e, koda lakoko ti ko si owo nilẹ yii.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI