Bo tilẹ jẹ pe a ko le f'idi rẹ mulẹ daadaa, ṣugbọn iroyin to tẹ wa lọwọ ti fi ye wa pe igbakeji aarẹ orileede yii, Ọjọgbọn Yẹmi Ọṣinbajo ti gba gbogbo owo to gbe silẹ f'awọn aṣoju oṣelu ti wọn lọ dibo nibi idibo abẹlẹ ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC fun ipo aarẹ to waye kọja yii pada.
Ọjọgbọn Yẹmi Ọṣinbajo lo jade lati du ipo aarẹ orileede Naijiria labẹ asia ẹgbẹ oṣelu APC, ṣugbọn to padanu s'ọwọ Aṣiwaju Bọla Ahmẹd Tinubu.
Ipo kẹta ni Ọṣinbajo ṣe ninu awọn oludije ti wọn jade du ipo ọhun.
AWIKONKO gbọ pe ipinlẹ Kwara nikan ni wọn di gbogbo ibo wọn fun Aṣiwaju Bọla Ahmẹd Tinubu,, gẹgẹ bi esi ibo to jade ṣe sọ.
Wọn ni ẹyin Tinubu ni gbogbo awọn aṣoju oṣelu ti a mọ si dẹligeeti, iyẹn 'Delegates' n'ipinlẹ Kwara wa patapata.
Ṣaaju ọjọ idibo abẹle la gbọ pe Ọṣinbajo lọ b'awọn aṣoju ti wọn yoo dibo lati Kwara, to si gbe owo kalẹ fun wọn lati le dibo fun un, ṣugbọn to jẹ pe ileri ori ahọn ni wọn ṣe fun un.
Lẹyin ti esi idibo ọhun jade, lo ṣẹṣẹ fi oju han sita wi pe ko si ẹnikan ṣoṣo lati ipinlẹ Kwara to dibo fun Ọjọgbọn Yẹmi Ọṣinbajo, Aṣiwaju Bọla Ahmẹd Yinubu ni gbogbo wọn ṣiṣẹ fun.
Pẹlu ibinu la gbọ pe Ọṣinbajo fi ran ọkan lara awọn ọmọ ẹyin rẹ, Onimọ-ẹrọ Tobi lati lọ fi awọn agbofinro dunkoko mọ gbogbo awọn aṣoju to gba owo naa, ti wọn ko si dibo, lati da owo pada.
Bayii ni esi idibo naa ṣe lọ si
South-West:
Lagos – 60 BAT - 55
Ekiti – 48 BAT - 05
Ogun – 60 BAT - 30
Osun – 90 BAT - 80
Oyo – 99 BAT - 85
Ondo – 54 BAT - 43
Total = 411 Total = 298
South-South:
Akwa Ibom – 93 BAT - 10
Bayelsa – 24 BAT - 10
Cross River - 54 BAT - 10
Delta – 75 BAT - 30
Edo – 54 BAT - 38
Rivers – 69 BAT - 01
Total = 369 Total = 99
South-East:
Abia – 54 BAT - 01
Anambra – 63 BAT - 01
Enugu – 51 BAT - 05
Ebonyi – 39 BAT - 01
Imo – 81 BAT - 02
Total = 288 Total = 10
North-East:
Adamawa – 63 BAT - 40
Bauchi – 60 BAT - 49
Gombe – 33 BAT - 25
Borno – 81 BAT - 74
Yobe – 51 BAT - 05
Taraba – 48 BAT - 30
Total = 336 BAT = 223
North-Central:
Kogi – 63 BAT - 00
Kwara – 48 BAT - 48
Benue – 69 BAT - 55
Plateau – 51 BAT - 23
Nasarawa – 39 BAT - 30
Niger – 75 BAT - 62
FCT Abuja – 18 BAT - 06
Total = 363 Total = 224
North-West:
Kaduna – 69 BAT - 40
Kano – 132 BAT - 120
Katsina – 102 BAT - 91
Kebbi – 63 BAT - 52
Jigawa – 81 BAT - 40
Sokoto – 69 BAT - 50
Zamfara – 42 BAT - 24
Total = 558 Total= 417
Grand Total =2,340
BAT Total = 1,271.
No comments:
Post a Comment