Gomina ana nipinlẹ Ogun, Sẹnetọ Ibikunle Amosun ti sọ pe fun anfaani ki ipo aarẹ le wa si ilẹ Yoruba loun ṣe juwọ silẹ lasiko eto idibo abẹle ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC to kọja yii.
O sọrọ naa lasiko to n ba awọn alatilẹyin rẹ ti wọn waa ki i kaabọ lati ilu Abuja to ti lọọ dije nibi ibo abẹle funpo aarẹ labẹ asia ẹgbẹ oṣelu APC, eyi to waye ni Gbọngan Alake, to wa ni Abẹokuta l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii.
Gomina tẹlẹ naa ni atilẹyin ti awọn gomina ilẹ Hausa ṣe fun awọn oludije lati apa Guusu lo fa a ti oun fi juwọ silẹ fun Aṣiwaju Bọla Tinubu lasiko idibo abẹle naa.
O ṣalaye pe oun ko ka a si dandan lati di aṣoju ti ẹgbẹ yoo fa kalẹ lasiko idibo abẹle naa. O ni ida ogun ninu ọgọrun ni ifẹ ọkan oun lati di oludije fun ẹgbẹ naa, nigba ti ida ọgọrin ọkan oun wa fun ifẹ ilẹ Yoruba ati orileede Naijiria.
Siwaju si i, o ni ohun ti awọn wo ti igbesẹ naa fi waye pẹlu awọn oludije lati ilẹ Yoruba ni pe bi awọn ba fẹ ki ipo aarẹ wa si ilẹ Yoruba, awọn gbọdọ fi imọ ṣọkan, ki awọn si gbagbe erongba ọkan ẹnikọọkan fun anfaani awọn eeyan agbegbe iha Guusu, paapaa ju lọ, ilẹ Yoruba.
O ni yatọ si Oloye Oluṣẹgun Ọbasanjọ, ko si ẹnikẹni, boya o ti ku tabi o wa laaye, to sin ipinlẹ Ogun bii toun.
Bẹẹ lo rọ awọn alatilẹyin rẹ pe gbogbo ifẹ, atilẹyin ati adura ti wọn n ṣe fun oun, ki wọn tubọ tẹsiwaju, ṣugbọn ki wọn nawọ rẹ si ẹni ti ẹgbẹ fa kalẹ lati dije dupo aarẹ lorukọ ẹgbẹ oṣelu APC, ki wọn si ṣe atilẹyin fun un ko le rọwọ mu lasiko ibo ọdun to n bọ.
No comments:
Post a Comment