Gbogbo awọn akẹkọọ kaakiri ipinlẹ Kwara l'ọjọ Aiku, Sannde to kọja ni wọn dide iwọde lati fi imọriri wọn han lori idagbasoke to de ba eto ẹkọ kaakiri ipinlẹ naa, ati anfaani t'awọn akẹkọọ n jẹ.
Iwọde naa ni wọn fi saami ayẹyẹ ayajọ ọjọ eto oṣelu awa-ara-wa, eyi ti ijọba ipinlẹ naa n fi si ojuṣe latigba to ti gba ijọba lọdun 2019.
Nibi iwọde ọhun ni apapọ ẹgbẹ awọn akẹkọọ yii ti ṣe ileri wi pe awọn yoo gbauruku ti ipadasipo Gomina AbdulRahman AbdulRazaq lẹẹkeji, pẹlu bi wọn ṣe sọ pe iṣakoso rẹ n tẹ awọn lọrun.
Ẹgbẹ kan ti wọn pe ni AbdulRahman AbdulRazaq Students' Support Group (AASSG) ti Kọmureedi Salami Wasiu Onidugbe jẹ olori wọn lo ṣe iwọde ọhun.
Nibẹ ni wọn ti jẹ ko di mimọ pe ipa gomina lati gbe ile ẹkọ Kọlẹẹji dide, sisan owo iranwọ lasiko, atunṣe awọn yara ikẹkọọ ati ọfiisi, gbigba awọn olukọ to dangajia, pẹlu awọn miran lo wu wọn lori lati ri i pe awọn gbaruku ti bi gomina naa yoo ṣe pada sipo lẹẹkeji, ko le tubọ raaye lati pari awọn akanṣe iṣẹ to dawọ le.
Ninu ọrọ Onidugbe to lewaju wọn o sọ pe
"A wa nibi lonii lati fi ye Gomina AbdulRahman AbdulRazaq wi pe o yẹ lẹni to n pada s'ipo naa lẹẹkeji, nitori to ti ṣe iṣẹ ribiribi nipa idagbasoke loriṣiriṣi ẹka eto iṣejọba, paapaa eto ẹkọ.
"Ẹni to ba ṣe daadaa lakọkọ ni lati pada lẹẹkeji. A ṣe agbekalẹ iwọde yii lati sọ fun gbogbo ọmọ ipinlẹ Kwara wi pe Gomina AbdulRazaq ti ṣe daadaa, fun idi eyi, o nilo lati ṣe saa keji."
No comments:
Post a Comment