Ìjọba Kwara ètò láti dẹ́kun àrùn tó n jẹyọ lára ọ̀bọ (Monkey Pox) - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Thursday, June 30, 2022

Ìjọba Kwara ètò láti dẹ́kun àrùn tó n jẹyọ lára ọ̀bọ (Monkey Pox)


L'Ọjọru, Wẹsidee ana ni ijọba ipinlẹ Kwara bẹrẹ eto ilera kan lati dẹkun arun to n jẹyọ lara ọbọ, eyi a mọ si Monkey Pox ti wọn kofiri rẹ lara awakọ kan lọsẹ to kọja yii.

Ilu Lafiagi to wa n'ijọba ibilẹ Edu ni wọn ti ṣawari arun naa, to si jẹ pe latigba naa ni wọn ti bẹrẹ igbesẹ, lojuna lati tete dẹkun rẹ.

Ileeṣẹ eleto ilera ipinlẹ naa, ati awon ile iṣẹ aladani eleto ilera kan la gbọ pe wọn tọwọ bọ iwe adehun lati ṣe idanilẹkọọ ati ayẹwo ọfẹ fun gbogbo awọn olugbe agbegbe ọhun.

Pẹlu idunnu ati ayọ la gbọ pe awọn araalu fi tẹwọ gba eto ọhun, ti wọn si jade lọpọ yanturu lati gba idanilẹkọọ ti wọn gbe wa fun wọn.


Awọn akọṣẹmọṣẹ eleto ilera ijọba ipinlẹ naa, to di mọ awọn oṣiṣẹ Disease Surveillance and Notification Officer (DSNO), ti Dọkita Fatimah Lah lewaju wọn, pẹlu awọn oṣiṣẹ ajọ World Health Organization, AFENET at'awọn miran la gbọ pe wọn kọwọrin lọ.

Oriṣiriṣi ọna ti awọn eeyan le gba lati dẹna ohun to n fa arun naa la gbọ pe wọn kọ wọn, ti awọn ara agbegbe naa si fi ara balẹ gba idanilẹkọọ to ye kooro.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI