Lojuna lati jẹ ki eto aabo to peye tubọ wa fun ẹmi ati dukia awọn araalu, ijọba ipinlẹ Kwara labẹ Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ti sọ pe ofin naa yoo bẹrẹ si i fi ẹsẹ mulẹ bayii fun gbogbo awọn to n gun ọkada ati awọn to n wa kẹkẹ ẹlẹsẹ mẹta ti a mọ si Maruwa lati maa wọ aṣọ kan naa.
Yatọ si aṣọ kan naa ti wọn pe ni Yunifọọmu, gbogbo ọlakada ati awọn to n wa maruwa ni yoo tun ni kaadi idanimọ, lati le mọ awọn to n sare wọle laaarin wọn.
Eyi lo waye lẹyin ti ijọba ipinlẹ Eko labẹ iṣakoso Gomina Babajide Sanwo-Olu fi ofin de awọn ọlọkada, ti wọn si ni ipinlẹ miran ni gbogbo awọn ọlọkada ti wọn le danu n'ipinlẹ Eko gba lọ, eyi ti ipinlẹ Kwara naa ko gbẹyin.
Iroyin to tẹ wa lọwọ sọ pe ọpọ awọn eeyan, paapaa ajoji ni wọn ti wọ ipinlẹ Kwara bayii lati maa fi ọkada pẹlu maruwa ṣiṣẹ aje, ti wọn si l'awọn kan fẹ maa fi jale ati jibiti kaakiri.
Eyi ni wọn lo mu ki ijọba Kwara dide lati bẹrẹ si i fun gbogbo awọn ọlọkada ati awọn oni maruwa ni kaadi idanimọ pẹlu aṣọ lati le da ojulowo mọ laaarin wọn, lojuna lati jẹ ki eto aabo to peye wa.
Ijọba Kwara ti sọ pe ọfẹ ni kaadi idanimọ ati awọn aṣọ naa to ti ni aami eto aabo lara, fun anfaani araalu si ni.
A gbọ pe ofin naa yoo bẹrẹ si i fi ẹsẹ mulẹ daadaa, bẹrẹ lati ọjọ kin-in-ni, oṣu kẹjọ, ọdun yii, ti wọn si n gba gbogbo awọn ọlọkada ati oni maruwa lamọran lati tete lọ gba kaadi idanimọ ati aṣọ ti wọn ko to di pe o pẹ ju.
Ninu atẹjade ti Ọgbẹni Temi Kọlawọle to jẹ akọwe fun
igbimọ ileeṣẹ to n ri sọrọ ilanilọyẹ eto irinna, Kwara State Transport
Sanitization Committee fi sita lo tun ti jẹ ko di mimọ pe gbogbo awọn ti ọwọ ba tẹ wi pe wọn ko ni awọn aami idanimọ yii ni wọn yoo le danu kuro ni ipinlẹ naa.
O ni gbogbo awọn ti wọn ba tun lọ orukọ miran si aṣọ ti ijọba ti pese silẹ fun wọn yii ni wọn yoo fi oju winna ofin, nitori pe wọn ko ni i faaye gba iwa ibajẹ, tabi lati maa lo anfaani eto ọhun fi ṣiṣẹ ibi.
No comments:
Post a Comment