Ìjọba Kwara bẹ̀rẹ̀ ìgbésẹ lórí ètò ìṣúná ọdún 2023 - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Thursday, June 30, 2022

Ìjọba Kwara bẹ̀rẹ̀ ìgbésẹ lórí ètò ìṣúná ọdún 2023


Ijọba ipinlẹ Kwara l'Ọjọru, Wẹside ana ti bẹrẹ ipade ita gbangba pẹlu awọn araalu lori eto iṣuna ọdun 2023 to n bọ lọna lojuna lato tẹsiwaju iṣejọba awa-ara-wa to ṣoju-ṣaara.

Gomina AbdulRahman AbdulRazaq nigba to n ṣalaye ọrọ rẹ sọ pe ipade ọhun ni lati gbọ erongba awọn araalu lori awọn nnkan ti wọn n fẹ lọdun to n bọ, lati tubọ le ṣe ju awọn eyi ti wọn ti n ṣe tẹlẹ lọ.


Igbakeji gomina, Ọgbẹni Kayọde Alabi nigba to n gba ẹnu ọga rẹ sọrọ, sọ pe ipade ita gbangba fun eto iṣuna ọdun to n bọ yoo bẹrẹ pẹlu aarin ẹkun gbungbun ipinlẹ naa, ti ipele keji yoo si waye niluu Lafiagi, ẹkun Ariwa Kwara.

O tun fidi rẹ mulẹ pe ipele kẹta ti wọn yoo fi kadi rẹ nilẹ ni yoo waye ni ẹkun Guusu ipinlẹ Kwara.



No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI