Ifọrọwanilẹnuwo ati idanwo igbega f'awọn oṣiṣẹ TESCOM ni Kwara waye lonii - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Saturday, June 18, 2022

Ifọrọwanilẹnuwo ati idanwo igbega f'awọn oṣiṣẹ TESCOM ni Kwara waye lonii


Ijọba ipinlẹ Kwara labẹ Gomina
AbdulRahman AbdulRazaq ti gbe awọn ọjọ ti ifọrọwanilẹnuwo yoo waye fun gbogbo oṣiṣẹ ajọ TESCOM nipinlẹ naa, iyẹn Teaching Service Commission sita.
 
Awọn oṣiṣẹ TESCOM ti ọdun 2018, 2019, 2020 ati 2021 ti wọn ti yẹ fun igbega la gbọ pe ajọ TESCOM sọ fun wi pe ki wọn lọ maa gbaradi lati kopa ninu ifọrọwanilẹnuwo ati idanwo lati bọ si pele to ga.
 
Gbogbo awọn oṣiṣẹ ati awọn olukọ, iyẹn Teaching and Non-Teaching Staff  ti ọrọ yii kan la gbọ pe wọn ti n mura silẹ fun ọjọ naa lasiko ti a pari akojọpọ iroyin yii.

Alaga apapọ fun ajọ TESCOM nipinlẹ naa, Mallam Bello Tauheed Abubakar lo fi ọrọ naa lede wi pe lẹyin ti Gomina AbdulRazaq ti bu ọwọ luu pe ki wọn lọ bẹrẹ eto igbega, lo mu ki wọn pinnu ọjọ ti eto ọhun yoo bẹrẹ.
 
Ninu atẹjade ti akọwe iroyin ajọ naa, Jide Abọlarin fi sita, lo ti jẹ ko di mimọ pe gbogbo awọn oṣiṣẹ ti wọn wa ni ipele keje titi de ipele kẹwaa, iyẹn Grade Level 07 to 10 ati awọn to wa ni ipele kẹrinla si ipele kẹtadinlogun, Grade Level 14 to 17 ni wọn yoo lanfaani lati kopa, to si jẹ ko di mimọ pe oni, ọjọ Abamẹta ti i ṣe Satide ni wọn yoo bẹrẹ niluu Ilọrin.
 
Abọlarin sọ pe ile-ẹkọ girama ti St Anthony Secondary School to wa niluu Ilọrin l'awọn ipele keje si ipele kẹwaa yoo ti ṣe ifọrọwanilẹnuwo ti wọn, bẹrẹ lati agogo mẹjọ si agogo mọkanla owurọ.
 
Bẹẹ lo sọ pe awọn to wa ni ipele kẹrinla si ikẹtadinlogun yoo ṣe idanwo ti wọn ni ile-ẹkọ C&S College, to wa niluu Ilọrin, bẹrẹ lati agogo mẹjọ aarọ si mọkanla aarọ bakan naa
 
O tun fi kun ọrọ rẹ wi pe awọn oṣiṣẹ ti wọn wa ni ipele keje si ipele kẹwaa, ati ipele kẹrinla si ipele kẹrindinlogun, iyẹn n'ijọba ibilẹ Kwara South ati Kwara North yoo tun ṣe idanwo ti wọn lonii, Satide, bẹrẹ lati agogo mejila ọsan si agogo marun-un irọlẹ, ati pe olu ileeṣẹ wọn nipinlẹ naa ni yoo ti waye.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI