Idi ti mo fi mu Okowa gẹgẹ bi igbakeji mi - Atiku - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Thursday, June 16, 2022

Idi ti mo fi mu Okowa gẹgẹ bi igbakeji mi - Atiku


Oludije sipo aarẹ orileede Naijiria labẹ asia ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party, PDP, Atiku Abubakar ti sọ pe Gomina ipinlẹ Delta, Ifeanyi Okowa ni ẹni toun fẹẹ lo gẹgẹ bi igbakeji oun.
 
Atiku lo sọrọ naa laipẹ yii lori ikanni ayelujara rẹ lati fi to gbogbo ọmọ Naijiria leti, bi wọn ti ṣe n reti ẹni ti yoo kede gẹgẹ bi igbakeji rẹ, ti wọn yoo jọ dije lọdun 2023 to n bọ lọna.
 
Iroyin to tẹ wa lọwọ sọ pe Gomina Nyesom Wike ti ipinlẹ Rivers ati Gomina Ifeanyi Okowa ni wọn wa nilẹ, ti Atiku n woju ẹni ti yoo mu laaarin wọn, ṣugbọn ni bayii, o ti kede ẹni ti ọkan rẹ yan sita.
 
Nigba to n kede, o ni "lati mu igbakeji mi jẹ ohun to ṣoro, ṣugbọn mi o bẹru lati gbe igbesẹ naa."

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI